PDP governors'meeting: Àwọn gómìnà PDP ní Buhari ti dojú ọrọ̀ ajé Nàìjíríà rú, wọ́n ké sí ilé aṣòfin àpapọ̀ láti fọwọ́ sí abá ìlànà ìdìbò Electorral bill fúnra wọn

Oríṣun àwòrán, Pdp governors forum
Awọn gomina ẹgbẹ oṣelu PDP ti pari ipade wọn ni ilu Portharcourt nibi ti wọn ti gbe bi nnkan ṣe n lọ si lorilẹede Naijiria yẹwo lọjọ Aje.
Lẹyin ipade ọhun, awọn gomina naa sọrọ soke pẹlu afẹnuko onikoko mẹsan an kan eyi ti gomina Aminu Tambuwal ka sita lorukọ wọn.
Awọn koko mẹsan an naa niwọnyii:
- Awọn gomina lẹgbẹ oṣelu PDP naa kan sara sawọn adari ẹgbẹ oṣelu naa fun bi eto idibo awọn adari ẹgbẹ to waye ldun 2021 ṣe lọ ni irọwọrọsẹ ati iṣẹ ti awọn adari ẹgbẹ naa n ṣe lati tun ẹgbẹ oṣelu naa ati orilẹ-ede Naijiria to pada.
- Awọn gomina naa tun rọ ileegbimọ aṣofin apapọ Naijiria lati tete jiroro lori aba eto idibo tuntun ti aarẹ da si wọn laya laipẹ yii
Eyi to wa nipa lilo agbara ti ofin Naijiria fun wọn lati fi aṣẹ si aba naa ko dofin lai fi ti aarẹ ṣe, nitori gẹgẹ bi ọrọ wọn, yiyanju ọrọ abadofin ilana eto idibo loju ọjọ ni ipa ribiribi lati ko fun aṣeyọri idibo.
- Ipade awọn gomina ipinlẹ tun kọminu lori bi ọrọ eto aabo ṣe da lorilẹ-ede Naijiria lakoko yii ati ọna ti awọn alaṣẹ n gba lati koju rẹ.
- Bakan naa lawọn gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP naa tun fi ẹdun ọkan wọn han lori ohun ti wọn pe ni bi aarẹ ko ṣe faramọ eto ọlọpaa ipinlẹ ninu ọrọ kan to sọ laipẹ yii.
Wọn si n rọ Buhari lati ṣe atunto ilana eto abo lorilẹede Naijiria; ki o si tun ya owo to jọju fun awọn ẹka aabo gbogbo lati ra awọn ohun eelo.
- Lori ọrọ aje, awọn gomina naa ni iyalẹnu lo jẹ fun awọn pe gbogbo koko ti orilẹede fi n yangan lori ọrọ aje lo ti dẹnukọlẹ ni Naijiria labẹ iṣejọba APC.
- Awọn gomina naa tun sọrọ lori ọrọ akoso epo rọbi ti ko si ẹni to lee sọ ni pato bi aṣuwọn apapọ orilẹede Naijiria ṣe duro si ati pe o to ki ijọba to wa lode bayii tete wa wọrọkọ fi ṣada lori rẹ.
- Bakan naa lo tun rọ awọn ọdọ ti wọn ti to ibo o di lati tete lọ forukọ silẹ fun idbo lati lee yan ẹni ti wọn fẹ lasiko idibo ọdun 2023.
Awọn gomina to wa nibi ipade naa ni gomina Aminu Waziri Tambuwal, ti ipinlẹ Sokoto, gomina Udom Emmanuel ti Akwa Ibom State, Gomina Douye Diri ti Bayelsa, Gomina Samuel Ortom lati Benue State ati Gomina Ifeanyi Okowa ti ipinlẹ Delta.
Bakan naa ni Ifeanyi Ugwuanyi to jẹ gomina ipinlẹ Enugu, Gomina Oluseyi Makinde ti ipinlẹ Ọyọ, Ahmadu Umaru Fintiri to jẹ gomina ipinlẹ Adamawa, gomina Bala Mohammed ti Bauchi ati Nyesom Wike to jẹ gomina ipinlẹ Rivers ati olugbalejo ipade naa.














