Adamawa Killing: Muhammed Alfa gún ìyàwó rẹ̀ ọlọ́mọ mẹ́jọ pa nítorí pé ó ń ti ilẹ̀kùn mọ́rí

Obe

Oríṣun àwòrán, Others

Àjọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Adamawa ti nawọ́ gán ọkùnrin kan ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta fún ẹ̀sùn gígún ìyàwó rẹ̀ ẹni ogójì ọdún tí ẹ̀mí sì fi bọ́ ní ara rẹ.

Afurasí ọ̀hún, Muhammed Alfa, tó ń gbé ní abúlé Lande, ìjọba ìbílẹ̀ Gombe eyi to wa ninu ìpínlẹ̀ Adamawa, ló ti kọ́kọ́ gun ìyàwó rẹ̀, Hapsat Muhammed lọ́bẹ rí léyìí tó ṣokùnfà tí ìyàwó fi kó kúrò ní ilé.

Ní ilé mìíràn tí Hapsat gbà lati maa gbe ló ti nílò ilẹ̀kùn tó sì gbìyànjú láti yọ ilẹ̀kùn ilé rẹ̀ tẹ́lẹ̀ to maa n ti mọri.

Èyí ló bí Muhammed nínú tó sì yọ ọ̀bẹ tó fi gun un ní ọrùn, tó sì ṣe béẹ̀ di èrò ọ̀run kí wọ́n tó gbe e dé ilé ìwòsàn.

Àwọn ọlọ́pàá nawọ́ gán afurasí náà lẹ́yìn tí Baálẹ̀ ìlú Lande, Jauro Babangida Boka fi ọ̀rọ̀ náà tó wọn létí.

Àkọlé fídíò, Ẹni bá láyà kó wá wọ̀ọ́! Ta ni Ìgè Àdùbí nílẹ̀ Oodua?

Ìwádìí fihàn wí pé ọmọ mẹ́jọ ni wọ́n bí fún ara wọn.

Kọmíṣọ́nnà àjọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ ọ̀hún, Mohammed Ahmed Barde tó pè fún ìwádìí ìjìnlẹ̀ sínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà rọ àwọn ènìyàn láti yé e ṣe ìdájọ́ lọ́wọ́ ara wọn.

Àkọlé fídíò, Fatimah Abode Lybia

Bákan náà ló ní kí wọ́n gbé afurasí náà lọ si ilé ẹjọ́ lẹ́yẹ ò sọkà kí ó le jẹ́ ẹ̀kọ́ fún àwọn mìíràn.

Àkọlé fídíò, Lori ọrọ Olubadan tuntun