Ogun farmers and herders clash: Ìkọlù darandaran àti àgbẹ̀ wáyé ní Ògùn, ẹni márùn-ún, ọ̀pọ̀ ilé bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ

Oríṣun àwòrán, Others
Kò dín ní ènìyàn márùn-ún tó ti pàdánù ẹ̀mí wọn níbi àkọlù tó wáyé láàárín àwọn darandaran àti àgbẹ̀ ní ìjọba ìbílẹ̀ Imeko-Afon, ìpínlẹ̀ Ogun.
Ìròyìn ní àwọn darandaran àti àwọn àgbẹ̀ Ohori ní ìlú Idofa kọjú ìjà síra léyìí tó ṣokùnfà pípàdánù ẹ̀mí àti dúkìá.
Àwọn ènìyàn Aworo ní ìjọba ìbílẹ̀ Àríwá Yewa ló ti kọ́kọ́ lé àwọn darandaran ọ̀hún kúrò ní ìlú wọn, tí wọ́n sì pa mẹ́ta nínú wọn àti àwọn màálù wọn.
- Lekan Balogun ni Olubadan kàn, kó sí àríyànjiyàn n;ibẹ̀ - Ladoja, àwọn afọbajẹ Ibadan sọ̀rọ̀
- Mo gba kádàrá pé mi ò lè bímọ nílùú tó jẹ́ pé ọmọ pọ̀ lára àwọn obìnrin
- Ìgbà tí òògùn ẹ̀jẹ̀ ríru lè ṣiṣẹ́ jù rèé- Onímọ̀
- Ẹlẹ́wọ̀n tẹ́lẹ̀ gboyè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ méjì lọ́gbà ẹ̀wọ̀n
- Kí gan-an là n pé ní Voodoo?
- Dandan ni kí agbára ìṣèjọba padà sí Gúsù Naijiria ní 2023 - Àwọn olórí ẹ̀yà ní Gusu
Àwọn Aworo ní àwọn darandaran náà ba oko àti omi àwọn jẹ́ nípa dída ẹran wọ ibẹ̀ ni wọn ṣe lé wọn.
Nígbà tó ń jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ náà, agbẹnusọ àjọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun, Abimbola Oyeyemi ní àwọn darandaran ọ̀hún látàrí à ti gbẹ̀san àwọn ènìyàn wọn tí wọ́n pa ni wọ́n ṣe ṣàkọlù sí ìlú náà padà.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé, ọ̀kadà, oko ni wọ́n sun níná, tí ọ̀pọ̀ ènìyàn sì ti sá kúrò nínú ìlú.
Oyeyemi wá sọ àrídájú rẹ̀ pé àwọn ń ṣiṣẹ́ láti fi póró òfin gbé àwọn tó ṣiṣẹ́ láabi náà.










