Olubadan tussle: Osi ilẹ Ibadan, Rashidi Ladoja ní awuyewuye lórí ọ̀rọ̀ oyè Olubadan ti parí, Lekan Balogun yóò joyè láìpẹ́

Ladọja, Makinde pẹlu awọn oloye ilẹ Ibadan kan

Oríṣun àwòrán, The cable

Edeaiyede to n waye lori ọrọ tani Ọba kan nilẹ Ibadan ti n ṣebi ẹni di afisẹyin ti eegun n fi aṣọ to si tun n dabi pe ọna ti wa ṣi daadaa bayii fun tun Olubadan, Oloye Lekan Balogun ti oye naa kan lati gun ori apere Ọba ilẹ Ibadan bayii.

Osi Olubadan ti ilẹ Ibadan, Gomina ipinlẹ Ọyọ nigbakan ri, Oloye Rashidi Ladọja to sọrọ lorukọ awọn igbimọ oloye agba ilẹ Ibadan.

Eyi waye lẹyin ipade idakọnkọ ti wọn ṣe pẹlu Gomina Seyi Makinde ṣalaye pe gbogbo awuyewuye lori ẹni ti ipo Olubadan tọ si lẹyin ti Ọba Saliu Adetunji Aje Ogugunisọ kini jade laye lọjọ keji oṣu kinni ọdun 2022.

Bi o tilẹ jẹ wi pe ọrọ oye jijẹ nilẹ Ibadan kii saba fa gbọnmisi omi o too nitori ato rẹ, sibẹ ti ọtẹ yii fẹ ri bakan pẹlu bi ato tuntun ti gomina ana ni ipinlẹ Ọyọ, Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi gbe sita pẹlu fifi awọn oloye ilẹ Ibadan kan jẹ Ọba alade.

Àkọlé fídíò, Ẹni bá láyà kó wá wọ̀ọ́! Ta ni Ìgè Àdùbí nílẹ̀ Oodua?

Lọna ati wa ojutu si awuyewuye naa lo ṣokunfa ipade ti gomina ipinlẹ Ọyọ Ṣeyi Makinde ṣe pẹlu awọn oloye agba nilẹ Ibadan ni ofiisi rẹ to wa lagbegbe Agodi nilu Ibadan lọjọ Satide.

Àkọlé fídíò, BIAFRA at 50: Ìhàlẹ̀ ológun ni Gowon ni ká kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀- Aladejẹbi

Nigba ti ipade naa si fi pari ti awọn Oloye naa jade, Sẹnetọ Ladọja ṣalaye pe gbogbo ariyanjiyan to n waye lori ọrọ naa lo ti jẹ rodo lo ree mumi.

O fidi rẹ mulẹ pe ẹnikan kii ba yimiyimi du imi o, ko si ẹni kan to n ba Oloye Lekan Balogun du ipo naa nitori oun ni o kan lori ato oye Ibadan lati jẹ Olubadan tuntun.

Àkọlé fídíò, Èmi ni mo yọ "wipe" fi nu omi ẹkún to ti gbẹ́ àti ikun imú nímú òkú ọmọ tí wọ́n gbé lé mi lọ́wọ́ - Ìyá Ojo Emmanuel

O ni nisisiyi ti wọn ti pabi-yanbidun ọrọ naa yekeyeke, awọn afọbajẹ yoo bẹrẹ eto gbogbo lọsẹ yii lati fi orukọ Olubadan tuntun ranṣẹ si gomina ipinlẹ Ọyọ fun igbọwọle, ti eto oye gbogbo yoku yoo si lee bẹrẹ ni pẹrẹu.

Àkọlé fídíò, Bí mo ṣe làlùyọ pẹ̀lú ìpèníjà ara tí èmi náà ń lọ ọ́fíìsì gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ ìjọba - Raymond Adegoke

Lara awọn to wa nibi ipade naa ni Ọtun Olubadan, Oloye Lekan Balogun; Osi Olubadan, Oloye Rashidi Ladọja; Ashipa Olubadan, Oloye Eddy Oyewole; Ẹkẹrin Olubadan, Oloye Abiọdun Kọla Daisi.

Àkọlé fídíò, Mo mọ èsì ọ̀rọ̀ kẹ̀, Queen Salawa Abeni ló kọ́kọ́ ta sí mi pé èmi 'Alaragbo ọmọ bàbá olójú kan' ní 1980s - Kuburat Alaragbo

Awọn miran to tun wa nibẹ ni Ẹkarun Olubadan, Oloye Amidu Ajibade; Balogun, Oloye Owolabi Olakuleyin; Ọtun Balogun, Oloye Tajudeen Ajibola; Osi Balogun, Oloye Lateef Adebimpe; Ashipa Balogun, Oloye Kolawole Adegbola; Ekerin Balogun, Oloye Bunmi Isioye; Ekarun Balogun, Oloye Dauda Azeez.

Àkọlé fídíò, Evangelist Funmilayo Adebayo Mummy G.O: Ìgbà tí mo wà ní ìjọ́ba òkùnkùn, gbogbo ayé ló fẹ́