Shepherd Bushiri church pastor shot dead: Bí wọ́n ṣe yìnbọn pa Pasitọ kan lórí òkè

APostle Eric Bhuka

Oríṣun àwòrán, PROPHET SHEPHERD BUSHIRI/FACEBOOK

Ọkan lára àwọn Pasito ìjọ Enlightened Christian Gathering (ECG) ti ṣalábàápàdé iku ojiji lásìkò tí wọn ń gbàdúrà lórí òkè àdúrà wọn ní South Africa.

EGC jẹ Sọọṣi nla kan ni orileede South Africa eyi ti Oniwaasu ara ilẹ̀ Malawi Shepherd Bushiri n ṣe adari fun.

Loju opo ayélujára Bushiri fúnra rẹ lo ti fi sita pe wọn yìnbọn pa Pasitọ Eric Bhuka.

O ni "ó dùn mi gidi gan láti gbọ́ ìròyìn aburu nipa iku Aposteli Eric Bhuka, ọkan lara awọn Pasitọ ECG ni South Africa.

"Ohun to tilẹ n da ọkan mi laamu ni pe lori oke adura ni wọn ti yinbọn pa Aposteli wa nibi to ti lọ gbadura ni igbaradi fun isin ọjọ Aiku.

Àkọlé fídíò, Fatimah Abode Lybia

Mo mọ riri rẹ Aposteli Eric. O wa, o waasu, o jere ọkan ati pe ni ipari irinajo aye rẹ yii, o ti pada lọ ibi ti gbogbo wa yoo pada lọ bi a b pari iṣẹ wiwaasu Jesu Kristi laye yii. Sun un re fun ogo Aposteli".

Shepered Bushiri

Oríṣun àwòrán, Prophet Bushiri/Facebook

Awọn ọmọ ijọ ECG naa ti n fi ọrọ ibanikẹdun wọn ranṣẹ si adari Bushiri ati idile oloogbe Eric Bhuka.

Ninu oṣu Kẹwa ọdun 2020 ni awọn ijọba fi panpẹ ọba mu Wolii Bushiri ati iyawo rẹ lori ẹsun jibiti to ni ṣe pẹlu ẹgbẹgbẹrun miliọnu dolar ati iwa jẹgudujẹra. Nigba to ya ni wọn tu wọn silẹ pẹlu beeli ninu oṣu Kọkanla ọdun 2020 pẹlu aṣẹ pe wọn gbudọ ko gbogbo iwe irina wọn le ijọba lọwọ.

Bakan naa ni ibẹrẹ ọdun to kọja, Bushiri padanu ọmọ rẹ obinrin ọmọ ọdun mẹjọ, Saint Israella ti wọn si sinku rẹ ni orilẹede Malawi.