Nyesom Wike: Gómìnà Wike dá rúgúdù sílẹ̀ láàárín ọlọ́pàá, Sífú dìfẹǹsì lórí ẹsùn fàyàwọ́ epo rọ̀bì

Aworan Gomina Wike atawọn ọga ọlọpaa kan

Oríṣun àwòrán, Nyesom ezenwo wike/twitter

Gomina ipinlẹ Rivers, Wike ti da rugudu silẹ laarin awọn ọlọpaa, atawọn sifu difẹnsi lẹyin to fi ẹsun kan awọn agbofinro kan pe wọn n ṣe fayawọ epo, wọn si n da awọn ibudo ipọnpo ti ko bofinmu silẹ kaakiri.

Gomina Wike, lasiko to n fun awọn alaga kansu nipinlẹ naa laṣẹ lati ko orukọ awọn eeyan to n da ibupo ipọnpo ti ko bofinmu silẹ ni ipinlẹ naa fi ẹsun kan awọn oṣiṣẹ ọlọpaa ati sifu difẹnsi, NSCDC kan to ni wọn ni ibudo ipọnpo nibẹ.

Gomina ipinlẹ Rivers tọka si ọga ọlọpaa agbegbe kan nibẹ pẹlu oṣiṣẹ ikọ to n gbogunti biba dukia ilu jẹ nileeṣẹ Sifu difẹnsi kan gẹgẹ bi apẹrẹ awọn agbofinro to n gbẹyin bẹbọ jẹ lori ọrọ fayawọ epo rọbi nipinlẹ naa.

Àkọlé fídíò, Ẹni bá láyà kó wá wọ̀ọ́! Ta ni Ìgè Àdùbí nílẹ̀ Oodua?

Wike ni: "O ṣeni laanu pe lorilẹede yii, awọn agbofinro lo tun n lọwọ ninu iwa fayawọ epo rọbi. O ṣe mi ni kayeefi o ọga ọlọpaa Kọmiṣọnna.

Mo dupẹ pe ẹ ti gbe ga ọlọpaa ilu Rumuji to ni ile ipọnpo rọbi ti ko bofinmu kuro, ṣugbọn mo fẹ ki ẹ gbe e kuro ni ipinlẹ yii patapata.

Mi o lee jẹ gomina ni ipinlẹ ti agbofinro yoo tun maa lọwọ ninu iwa fayawọ epo rọbi. Ẹ gbe e lọ si ipinlẹ yoowu ti wọn ba ti fi aye gba fayawọ epo rọbi."

Àkọlé fídíò, Èmi ni mo yọ "wipe" fi nu omi ẹkún to ti gbẹ́ àti ikun imú nímú òkú ọmọ tí wọ́n gbé lé mi lọ́wọ́ - Ìyá Ojo Emmanuel

Bakan naa lo ni wọn gbọdọ gbe oṣiṣẹ agbofinro sifu difẹnsi naa kuro pẹlu nitori iwa agbẹyinbẹbọjẹ patapata ni wọn n hu yii ti ko si yẹ ko jẹ awọn ti a fi si idi didẹkun iwa fayawọ epo gan an ni yoo maa lọwọ ninu rẹ.

Àkọlé fídíò, Evangelist Funmilayo Adebayo Mummy G.O: Ìgbà tí mo wà ní ìjọ́ba òkùnkùn, gbogbo ayé ló fẹ́

Awọn ẹsun ti Gomina Wike la mọ awọn oṣiṣẹ ọlọpaa ati NSCDC yii ti n da ọpọlọpọ rugudu silẹ laarin agbo ileeṣẹ agbofinro mejeeji yii ti awọn alaṣẹ wọn si ti n gbe igbesẹ lori ọna ati ṣe afọmọ ẹrẹ ti igbesẹ naa taba aṣọ ala ileeṣẹ agbofinro wọn.

Àkọlé fídíò, BIAFRA at 50: Ìhàlẹ̀ ológun ni Gowon ni ká kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀- Aladejẹbi

Iroyin sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti gbe ọga ọlọpaa torukọ rẹ jade lori iwa ibajẹ naa kuro lagbegbe naa, wọn si ti gbe igbimọ oluwadi kan kalẹ labọ ga ọlọpaa ACP kan lati tan ina wadii iṣẹlẹ naa.

Àkọlé fídíò, Lori ọrọ Olubadan tuntun