Bode George vs Bola Tinubu: Ẹgbẹ́ olùpolongo kan ní àgbọ̀nrín èṣín sì ni Bode George ń jẹ lọ́bẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ Tinubu

tinubu ati bode george

Oríṣun àwòrán, other

Ẹgbẹ olupolongo kan fun Aṣiwaju Bola Tinubu ti da esi ọrọ pada fun eekan ẹgbẹ oṣelu PDP, Oloye Bode George lori ọrọ to sọ pe awada kẹrikẹri ni erongba Tinubu lati dupo aarẹ ni Naijiria.

Bode George

Oríṣun àwòrán, @Bode George

Àkọlé àwòrán, Bode George

Ẹgbẹ naa ti ibujoko rẹ wa ni ipinlẹ Akwa Ibom ni ọrọ ti Oloye George sọ fihan pe alatako ti ko mọ bi nkan ṣe n lọ ni o jẹ.

Oloye ti kọkọ sọ pe iru eeyan bii Tinubu kọ lo yẹ fun ipo aarẹ orilẹede Naijiria.

''Ẹ wo bi Tinubu ṣe ṣe ọrọ ipinlẹ Eko baṣu baṣu, o ya ni lẹnu pe Tinubu le gbero lati dupo aarẹ Naijiria.

Tinubu n tan ara rẹ jẹ nio lori erongba rẹ lati dije fun ipo aarẹ Naijiria,'' Bode George lo sọ bẹẹ.

Àkọlé fídíò, Young Tolibian

Ṣugbọn nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, alakoso ẹgbẹ olupolongo fun Tinubu nipinlẹ Akwa Ibom, Ifiok Inyang, ni lootọọ ni iwe ofin Naijiria faye gba ki eeyan sọrọ lawujọ.

''Amọ, Bode George ti ṣi anfaani yii lo lẹyin to tabuku Tinubu ẹni to jẹ ogbontagi oloṣelu to tun jẹ ilumọọka kaakiri Naijiria.

Àkọlé fídíò, Arinrinoge ti eyin rẹ kán

Iwọfa lẹnu ṣa, Bode George le sọ ohun to ba wu hu amọ lori ọrọ to sọ pe awada kẹrikẹri lọrọ erongba Tinubu lati dupo aarẹ, o tumọ si pe Bode George ko mọ bo ṣe n lọ ni.

Lai ni deena pẹnu, kikede erongba Tinubu lati dupo aarẹ jẹ iroyin oṣelu to dara julọ julọ lọdun yii.

Àkọlé fídíò, Lori ọrọ Olubadan tuntun

Ikede yii ti mu ki ọpọlọpọ ọmọ ẹgbẹ APC maa kede erongba wọn bakan naa lati dije fun ipo aarẹ.

Ohun kan to yẹ kawọn ọmọ Naijiria mọ ni pe Tinubu kede lati dupo aarẹ Naijiria gẹgẹ bi idahun si ọpọ eeyan bẹ ẹ lati dije fun ipo naa.

Àkọlé fídíò, Ọmọ ọdún mẹ́ta ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí ní lu ìlù, kí n tó di onílù Yinka Ayefele

''Bode George, jáwọ́ lápọ̀n tí ò yọ̀, ìfẹ́ aráàlú ló mú Tinubu fẹ́ dupò ààrẹ lọ́dún 2023''

Ọpọ lo gbagbọ pe Tinubu lo to gbangba sun lọyẹ lati wa ojutu si ọrọ-aje to dẹnu kọlẹ ati eto abo to mẹhẹ ni Naijiria,'' Iyang lo sọ bẹẹ.

Àkọlé fídíò, Evangelist Funmilayo Adebayo Mummy G.O: Ìgbà tí mo wà ní ìjọ́ba òkùnkùn, gbogbo ayé ló fẹ́