Ikú Esther Anguju ní ìpínlẹ̀ Nasarawa dá inú fu, àyà fo kalẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n fẹ̀sùn ìpànìyàn kan ọkọ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Others
Obìnrin kan, Esther Aya Anguju ti ṣe kòńgẹ́ ọlọ́jọ́ rẹ̀ nígbà tí òun àti ọkọ rẹ̀, Agga Sunday Yakub jọ ń ṣe àríyànjiyàn lórí ọ̀rọ̀ ilé túntúnṣe.
Gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹbí Esther ṣe wí, ọjọ́ keje oṣù, kìíní ni ó jáde láyé ní agbègbè Sabon Pegi Shabu ní ìpínlẹ̀ Nasarawa.
Àwọn mọ̀lẹ́bí Esther fi ẹ̀sùn kan Sunday wí pé ó lu ìyàwó rẹ̀ ṣùgbọ́n àwọn ara àdúgbò ní àríyànjiyàn lásán ló wáyé láàárín wọn tí Esther sì ṣubú lásìkò tí àríyànjiyàn ń lọ lọ́wọ́.
- Gani Adams ṣàlàyé bí ìjọba àpapọ̀ ṣe ń dènà ìtúsílẹ̀ Sunday Igboho ní àhámọ́
- Ìkọlù darandaran àti àgbẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ògùn: Ènìyàn márùn-ún, ọ̀pọ̀ ilé bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ
- Lekan Balogun ni Olubadan kàn, kó sí àríyànjiyàn níbẹ̀ - Ladoja, àwọn afọbajẹ Ibadan sọ̀rọ̀
- Mo gba kádàrá pé mi ò lè bímọ nílùú tó jẹ́ pé ọmọ pọ̀ lára àwọn obìnrin
- Ìgbà tí òògùn ẹ̀jẹ̀ ríru lè ṣiṣẹ́ jù rèé- Onímọ̀
Inú fu, àyà fo ti gba àdúgbò náà bí àwọn mọ̀lẹ́bí Esther ṣe fi ọlọ́pàá gbé Sunday tí wọ́n sì ń bèrè fún pípa òun náà.
Agbẹnusọ àjọ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Nasarawa, Rahman Nansel ní àwọn ti nawọ́ gán afurasí náà ṣùgbọ́n ìwádìí ṣì ń lọ lọ́wọ́ láti ṣàwárí ohun tó fa ikú Esther.
Nansel ní ṣíṣe àyẹ̀wò òkú náà ló le fi ìdí òtítọ́ hàn, tó sì ní Kọmíṣọ́nnà àjọ ọlọ́pàá tí ń bá àwọn mọ̀lẹ́bí Esther sọ̀rọ̀ láti ṣe sùúrù lórí ọ̀rọ̀ ọ̀hún.

Oríṣun àwòrán, Others
Nígbà tó ń sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ gan an fún ikọ̀ ìròyìn BBC, Sunday Wilson tó jẹ́ ọmọ ọkọ Esther ní bàbá òun lé kápẹ́ńtà tó ń bá àwọn kan nẹ́ẹ̀tì sójú fèrèsé ilé àwọn bí ó ṣe rò wí pé Esther ni ó ń ṣe é.
Ó ní èyí ló bí Esther nínú tó fi jáde láti sọ̀rọ̀ sí ọkọ rẹ̀ pé yóò jẹ́ kí ẹ̀fọn àti eṣinṣin máa wọlé.
Ó fi kun un pé Sunday dún kokò mọ́ Esther wí pé kó kúrò nílé òun bí bẹ́ẹ̀ kọ́ òun yóò pá ṣùgbọ́n Esther yarí pé òun kò ní lọ àti wí pé wọ́n máa ń jà lórí ta ló nilé.
Nínú ọ̀rọ̀ ti rẹ̀, ẹ̀gbọ́n Esther, Orver Aya ní Sunday ti máa ń na Esther tẹ́lẹ̀ àti pé kìí gbọ́ bùkátà kankan nínú ilé.
Ó ní ọ̀pọ̀ ìgbà ní Esther máa ń fi ẹjọ́ sun òun, tí nínà náà si peléke sí i lẹ́yìn ìgbà tí ìyá àwọn jáde láyé.















