Yoruba Nation: Ìjọba Nàìjíríà ló ń dún mọ̀huru mọ́ Benin Republic lati dé Sunday Igboho mọ́ àhámọ́ - Gani Adams

Aworan Sunday Igboho ati Iba Gani Adams

Oríṣun àwòrán, Other

Aarẹ Ọna kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams ti fi aidunu rẹ han lori bi Oloye Sunday Adeyẹmọ ṣi ṣe wa ni ahamo.

O ni ko tẹ oun lọrun bi ẹni ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ṣe n pẹ ni atimọle lorilẹede Benin Republi.

Koda, Iba Adams ṣalaye pe o da oun loju pe ijọba apapọ Naijiria lo wa nidi bi wọn ṣe ti lẹkun ahamọ mọ Sunday Igboho ti wọn si ju kọkọrọ rẹ nu.

Ninu ọrọ kan to sọ nibi ipade akọroyin kan to fi n sami ayajọ ọdun kẹrin rẹ nipo gẹgẹ bii aarẹ ọna kakanfo ẹlẹkarundinlogun ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams ni ko si ijọba to nifẹ awọn eeyan rẹ ti yoo gba ki iru iṣẹlẹ bẹẹ waye.

"Ipe fun idasilẹ orilẹede Yoruba ni Sunday Igboho pe, ko jagun, bẹẹ ni ko si gbe ibọn, ijijangbara alaafia lo n ba kiri.

Ijọba ran awọn agbofinro lọ baa nile, wọn pa eeyan meji nibẹ ti wọn ko si tii fi oku wọn silẹ titi di bi a ṣe n sọrọ yii."

Àkọlé fídíò, Èmi ni mo yọ "wipe" fi nu omi ẹkún to ti gbẹ́ àti ikun imú nímú òkú ọmọ tí wọ́n gbé lé mi lọ́wọ́ - Ìyá Ojo Emmanuel

Gani Adams ni iwadii oun ti fihan pe ijọba Naijiria n du mọhuru mọ ijọba Benin Republic ni wọn fi n tilẹkun ọgba ẹwọn mọọ lai pe e lẹjọnile ẹjọ.

O wa rọ Aarẹ Buhari lati tu okun lọrun Igboho ati Nnamdi Kanu nitori ominira ati idagbasoke agbegbe wọn ni wọn n ja fun.

Àkọlé fídíò, Ẹni bá láyà kó wá wọ̀ọ́! Ta ni Ìgè Àdùbí nílẹ̀ Oodua?