2023: Dandan ni kí agbára ìṣèjọba padà sí Gúsù Naijiria ní 2023 - Àwọn olórí ẹ̀yà ní Gusu

Edwin Clark ati Ayo Adebanjo ati olori miran

Oríṣun àwòrán, others

Agbarijọpọ ẹgbẹ awọn olori ni Gusu ati aarin gbungbun Naijiria ti fẹnuko pe dandan ni ki agbara iṣejọba bọ si ẹun Gusu ni ọdun 2023.

Nibi ipade pajawiri kan ti wọn ṣe nilu Abuja lọjọ Ẹti, ọjọ kẹrinla, oṣu Kinni, ni wọn ti sọ pe iwe ofin ti Naijiria n lo lọwọ ku diẹ kaato.

Alaga ipade naa, Oloye Ediwn Clark sọ pe nkan to bojumu ni ki ipo aarẹ bọ si Gusu Naijiria, lẹyin ti ẹun Ariwa ti gbadun rẹ fun ọdun mẹjọ.

Ninu atẹjade ti wọn fi sita lẹyin ipade naa, wọn rọ awọn ẹgbẹ oṣelu ni Naijiria, to n fẹ atilẹyin lati awọn ẹkun to wa ni Gusu Naijiria pe wọn gbọdọ fun oludije lati Gusu ni tikẹẹti wọn.

Bakan naa ni wọn tẹnumọ pe awọn n fẹ ki atunto waye nipa iwe ofin tuntun ti yoo fi aaye gba akoyawọ, idajọ ododo ati igba aye to dọgba.

Wọn tun ke si awọn gomina to wa ni gbogbo ipinlẹ ni Gusu Naijiria, lati fi ara wọn jin fun ipolongo fun atunto Naijiria ti ipilẹ iṣọkan rẹ duro lori akoyawọ, idajọ ododo ati igba aye to dọgba.

Lara awọn to tun wa nibi ipade naa ni olori ẹgbẹ Afenifere lati Iwọ-oorun Gusu, Oloye Ayo Adebanjo, aarẹ ẹgbẹ awọn ẹya Igbo, Ohaneze Ndigbo lati Ila-oorun Gusu, Ọjọgbọn George Obiazor, Sẹnetọ Emmanuel Ibok Essien to jẹ alaga Pan Niger Delta Forun lati Gusu-Gusu ati Ọmọwe Pogu Bitrus, alaga Middle Belt Forum lati aarin gbungbun Naijiria.