Fake army general Bolarinwa Oluwasegun: Ọwọ́ tẹ ọ̀gágun sọ́jà ayédèrú tó fi ipò lu jìbìtì owó N270m

Oríṣun àwòrán, EFCC. TWITTER
Ọwọ ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria, EFCC ti tẹ ayederu ọgagun sọja kan, Bolarinwa Oluwasegun lori ẹsun jibiti N270m.
Afurasi ọhun ni a gbọ pe o n pe ara rẹ ni ọgagun ni ileeṣẹ ọm'ogun orilẹede Naijiria.
Ati wipe o purọ fun ileeṣẹ Kodef to n ri si kiko ẹru jade lati ibudokọ oju omi pe Aarẹ Muhammadu Buhari ti fẹ yan oun gẹgẹ bí olori ọmọ ogun orilẹ, COAS.

Oríṣun àwòrán, EFCC. TWITTER
- Ọkùnrin tó gbìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ìya rẹ̀ láti fi àbúrò rẹ̀ ṣẹ́ṣó kó sí gbaga Ọlọ́pàá
- Háà, nǹkan ṣe mí! Ikú pa ọ̀kan lára àwọn aláànú mi - Yinka Ayefele
- Ọkùnrin tó gbìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ìya rẹ̀ láti fi àbúrò rẹ̀ ṣẹ́ṣó kó sí gbaga Ọlọ́pàá
- 'Mo mọ̀ pé ọmọ mi tí wọ́n ló pa ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ n mu igbó, ó sì ní àìsàn ọpọlọ'
- Wo owó gọbọi tí Nàíjíríà àti orilẹ̀èdè míì ní àgbáyé pàdánù torí wọn ti ojú òpó ayélujára
- Háà! Akẹ́kọ̀ọ́ forí gbálẹ̀, o di èrò ọ̀run ní Ondo
Ọgbẹni Olusegun sọ fun ileeṣẹ Kodef pe oun nilo iranwọ owo lati rii pe Buhari foun ni ipo naa.
A gbọ wipe afurasi yii kọ lẹta ayederu iyansipo gẹgẹ bi olori ọm'ogun orilẹ lorukọ aarẹ eleyii to fihan ẹni to lu ni jibiti gẹgẹ bi ẹri.
Gẹgẹ bi atẹjade ti EFCC fi sita, Ọjọru ọjọ kejila oṣu kinni ọdun 2021 yii ni ajọ naa gbe afurasi ọhun nile rẹ lagbegbe Alagbado niluu Eko.
Awọn nkan ti wọn ri ni ile rẹ ni ibọn mẹfa, ọta ibọn mẹta, ọpa ati oriṣiiriṣii ayederu iwe.
















