Twitter Ban: $1.5bn ni Nàíjíríà sọnù torí bó ṣe ti ojú òpó ayélujára pa

A woman in Ghana using a phone with the Twitter logo in the background

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Orilẹede Naijiria ni adanu nla ba julọ laarin awọn orilẹede ilẹ Afirika to ti oju opo ayelujara pa.

Gẹgẹ bi iwadi tuntun kan lagbaye to da lori ipa ti mimọọmọ ti oju opo ayelujara n ni lori ọrọ aje se wi, Naijiria lo sikeji ninu awọn orilẹede to padanu owo julọ lagbaye tori pe wọn ti oju opo ayelujara pa.

Orilẹede Naijiria si lo n tọ orilẹede Myanmar lẹyin, eyi to sọ owo to to biliọnu mẹta o din diẹ Dọla nu lasiko to ti oju opo ayelujara pa.

Oni, ọjọ Kejila osu Kinni ọdun 2022 si ni orilẹede Naijiria gbe ẹsẹ kuro lori ofin to fi de oju opo Twitter lati sisẹ jakejado orilẹede naa.

Orilẹede Ethiopia si lo se ipo keji laarin awọn orilẹede Afirika yi ọrọ yii kan, to si padanu owo to to miliọnu mẹrinlelọgọjọ ati aabọ dọla ($164.5m).

Orilẹede Sudan lo wa ni ipo kẹta laarin awọn orilẹede ti titi oju opo ayelujara se akoba fun, to si sọ owo to to miliọnu lọna mọkanlelaadọjọ o le diẹ dọla ($151.6m) nu.

Orilẹede Uganda lo se ipo kẹrin pẹlu miliọnu lọna aadọfa o din diẹ to padanu ($109.7m).

O le ni idaji awọn orilẹede mọkanlelogun ti wọn ti oju opo ayelujara pa ni Afirika to wa ni ẹkun asalẹ Sahara.

Awọn orilẹede moran to wa ni ẹkun naa, to padanu owo nidi igbesẹ titi oju opo ayelujara pa ni Burkina Faso, to padanu owo to to miliọnu mẹrindinlogoji o din diẹ dọla ($35.9m).

Orilẹede Eswatini n tiẹ lo sọ owo to to miliọnu mẹta o din diẹ dọla nu ($2.9m), ti orilẹede olominira Congo si padanu miliọnu meji ati aabọ dọla ($2.5m).

Orilẹede Zambia lo padanu miliọnu meji o din diẹ dọla ($1.8m), ti Chad si sọ owo to to miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta dọla nu ($1.6 million).

Orilẹede Senegal naa padanu ẹgbẹrun lọna okoolelọọdunrun ati diẹ dọla ($323,953) nigba ti orilẹede South Sudan padanu owo to to ẹgbẹrun lọna ọtalerugba ati diẹ dọla ($269,987).

Ni ọdun to kọja, awọn orilẹede to wa ni ẹkun asalẹ Sahara lo padanu apapọ owo to to biliọnu meji o din diẹ dọla ($1.9bn) nitori bi ijọba se gbe awọn oju opo ayelujara ti pa, ti owo naa si tun ju bẹẹ lọ ni ọdun 2020.

Àkọlé fídíò, Mo mọ èsì ọ̀rọ̀ kẹ̀, Queen Salawa Abeni ló kọ́kọ́ ta sí mi pé èmi 'Alaragbo ọmọ bàbá olójú kan' ní 1980s - Kuburat Alaragbo

Iwa ifẹhonuhan amọọmọ se awọn ijọba orilẹede yii jakejado agbaye lo mu ki wọn padanu owo to to biliọnu marun ati miliọnu marundinlaadọta dọla ($5.45bn).

Ọpọ idaji igbesẹ fifi ẹhonu han nipa titi oju opo ayelujara yii lo jẹ ara aayan awọn ijọba naa lati se akoso iwọde ati eto idibo.

Gẹgẹ bi abọ iwadii kan ti ikọ kan to n sisẹ iwadii nipa aabo itakun agbaye Top10VPN to kalẹ silẹ UK gbe sita, awọn idi yoku ni sise akoso iroyin to n de setigbọ araalu lasiko rogbodiyan, eto idibo ati iditẹgbajọba.

Ni orilẹede Uganda, se ni wọn gbegile lilo oju opo ayelujara ni aisun eto idibo gbogbo gboo ilẹ naa to waye ni ọjọ Kẹrinla osu Kinni ọdun 2021.

Àkọlé fídíò, Sanya Adegbaye blind Yoruba teacher: Orí kí ojú mi lè là ni gbogbo owó Kòkó bàbá mi run sí

Ijọba ilẹ naa si lo pasẹ fun awọn ileesẹ ẹlẹrọ ibaraẹnisọrọ lati gbe igi di awọn oju opo ibadọrẹpọ lori ayelujara gẹgẹ bii ọna lati gbẹsan.

Gẹgẹ bi abọ iwadi ti ikọ Top10VPN gbe jade ti wi, ni tibu tooro agbaye, mẹta ninu mẹrin igbesẹ bi ijọba se n gbẹsẹ le lilo awọn oju opo ayelujara lo nii se pẹlu iwa titẹ ẹtọ ọmọniyan loju.

Orilẹede Myanmar nikan si ni orilẹede ti gbigbegi le lilo oju opo itakun agbaye se akoba fun julọ ni agbaye nitori bo se padanu owo to to biliọnu mẹta o din diẹ dọla ($2.8bn),

Orilẹede Naijiria si tẹle pẹlu bo se sọ owo to to biliọnu kan ati miliọnu lọna marundinlaadọta dọla nu ($1.45bn) nigba ti orilẹede India wa ni ipo kẹta pẹle bo se padanu owo to to miliọnu lọna ọ̀rinlelẹẹdẹgbẹta ati mẹta dọla ($583m).

Àkọlé fídíò, Evangelist Funmilayo Adebayo Mummy G.O: Ìgbà tí mo wà ní ìjọ́ba òkùnkùn, gbogbo ayé ló fẹ́

Abọ iwadi naa ni wọn gbe kalẹ lati ipasẹ sise ọfintoto bi wọn se n gbegi dina oju opo ayelujara eyi tawọn ijọba lawọn orilede lagbaye n se.

Akọsilẹ yii ni wọn wa lo lati se isiro ipa ti igbesẹ titi awọn oju opo ayelujara n ni ati bo ti n se akoba fun eto ọrọ aje.

Lara awọn akoba naa dida iwulo amulo intanẹti duro, pipa deta ati bawọn oju opo ori ayelujara ko se ni sisẹ.

Awọn ẹrọ igbalode ti wọn fi n se odiwọn amulo oju opo ayelujara, ti atọna rẹ si n wa lati ọdọ Banki agbaye, ẹgbẹ awọn ileesẹ ẹrọ ibaraẹnisọrọ lagbaye, Eurostat ati akọsilẹ eeyan to wa ni Amẹrika si ni wọn lo.