Twitter ban: Èrò ọmọ Naijiria ṣọ̀tọ̀tọ̀ lórí ìgbésẹ̀ ìjọba àpapọ̀ láti gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí Twitter

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Lẹyin ti ijọba apapọ kede pe awọn ti gbẹsẹ kuro lori ikanni Twitter ni Naijiria, oriṣiriṣi ọrọ ni awọn eeyan ti n sọ lori igbesẹ ọhun.
Bi awọn ọmọ Naijiria kan ṣe ri igbesẹ naa gẹgẹ bii eyii to tọ, lawọn mii ri bi igba ti eeyan ba n fi akoko ṣofo nitori awọn ko fi igba kankan fi oju opo Twitter silẹ.
Awọn mii ẹwẹ n sọ pe gbesẹ ijọba apapọ lati tun faye gba Twitter ko ṣẹyin eto idibo gbogbo ti yoo waye lọdun 2023.
Ni ti gbajugbaja adẹrinpoṣonu nni Debo Macaroni, o kọ ọ sita bi ọrọ si ijọba pe "Ẹnh ẹẹh, ṣe o ti suu yin abi? Ẹ kaab pada o. Ẹyin funra yin l gbẹs le ara yin kii ṣe Twitter. Ẹyin lẹ lọ! Awa o figba kankan lọ ibi kankan o."

Oríṣun àwòrán, DeboMacaroni
Lara awọn to ni irufẹ erongba pe tori idibo ọdun 2023 ni ijọba ṣe ṣe bẹẹ ni Jide Ogunsaya to ni o ṣeeṣe ko jẹ pe ijọba gbẹsẹ kuro lori Twitter nitori anfani ati ṣe ipoolongo eto idibo lori ikanni naa ni.

Oríṣun àwòrán, Jide Ogunsaya
Marline Oluchi naa gbagbọ pe tori eto idibo ọdun 2023 ni ijọba ṣe gbẹsẹ kuro lori Twitter.

Oríṣun àwòrán, Marline Oluchi
Lori twitter, awọn kan dupẹ lọwọ awọn ileeṣẹ VPN ti wọn fi n gba ọna ẹyin wọ oju opo naa, bẹẹ naa ni wọn si n ki awọn ọmọ naijiria ti ko lo VPN lati wọ oju opo naa pada kaabọ soju opo ọhun.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Inu awọn mii n dun pe wọn ti ni anfaani lati lo Twitter lai lo VPN.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Awọn ohun mii ti awọn ọmọ Naijiria n sọ lori Twitter ree.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3

End of X post, 4

End of X post, 5
Wo ìdí tí ìjọba Naijiria ṣẹ̀ṣẹ̀ gbẹ́sẹ́ kúrò lórí òfin tó fi de Twitter lẹ́yìn oṣù Méje

Oríṣun àwòrán, femi adesina
Ijọba apapọ ti gbẹsẹ kuro lori ẹrọ Twitter ni Naijiria lẹyin oṣu Meje to fofin de oju opo naa.
Ikede yii lo waye ninu atẹjade kan ti alaga igbimọ to n ri si ọrọ naa, Kashifu Inuwa Abdullahi fi lede niluu Abuja.
Atẹjade naa ni "Ijọba apapọ ti ran mi lati kede fun awọn araalu pe Aarẹ Muhammadu Buhari ti paṣẹ ki wọn ka ofin ti won fi de Twitter nilẹ, lati aago mejila oru, ọjọ kẹtala, oṣu Kinni, ọdun 2022 yii."
- A gbọ́dọ̀ padà sí ìlànà tà ń gbà jẹ Olubadan tẹ́lẹ̀ – Seyi Makinde
- De-General, àwọn mẹ́ta mìíràn wọ pańpẹ́ àjọ NDLEA torí egbògi olóró
- Wo àwọn ǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Alao Akala tó dágbére fáyé lẹ́ni ọdún 71
- Oluwo gbóríyìn fún Awujale, Akarigbo fún àyípadà òfin lórí àṣà àtijọ́ fún yíyàn Ọba, ṣíṣe ìsìnkú Ọba
- Pásítọ̀ David Ibiyeomie, adarí ìjọ Salvation Ministry tò dàwó sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà
- Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo tẹ́lẹ̀, Adebayo Alao-Akala ti jáde láyé
- Ọkọ mi pa ọmọ wa mẹ́ta, o kó òkú wọn sínú fírísà - Milliscent Amadikwa
- Ọ̀dọ́ márùn-ún forí la ikú nínú oko lọ́wọ́ agbébọn tó tún ṣèkọlù l'Ondo
"Aṣẹ yii waye lẹyin lẹta kan ti minisita to n ri si eto ibaraẹnisọrọ ati eto ọrọ aje ori ayelujara, Ọjọgbọn Isa Ali Ibrahim, kọ si Aarẹ".
"Ninu lẹta naa ni minisita ọhun ti jabọ fun Aarẹ ibi ti igbimọ ti wọn gbe kalẹ ba isẹ de, to si tun bere fun aṣẹ lọwọ Aarẹ pe ki wọn wọgile ofin ti wọn fi de Twitter".
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 6
Ṣaaju akoko yii ni ijọba aapọ ati Twitter ti kọkọ n fọrọjomitooro ọrọ lori bi wọn yo gbẹsẹ kuro lori ikanni naa, lori awọn idi kan.
Gẹgẹ bii ohun ti Ali Ibrahim sọ, ileeṣẹ Twitter ti gba lati ṣe ohun ti ijọba Naijiria n fẹ.
O ni "Adehun wa pẹlu Twitter yoo ran Twitter lọwọ lati le gbooro si ni Naijiria, ati pe ijọba apapọ yoo pese anfani to yanranti fun Twitter lati tunbọ ṣe aṣeyọri ni Naijiria".
Inu oṣu Kẹfa, ọdun 2021 ni Aarẹ Muhammadu Buhari gbẹsẹle Twitter ni Naijiria lẹyin ti ileeṣẹ naa yọ ọrọ to kọ lori ikanni ọhun bi ẹni yọ jiga.

Oríṣun àwòrán, @ulxma
Twiiter sọ lasiko naa pe ọrọ kobakungbe ni Aarẹ Buhari kọ loju opo naa, ati pe irufẹ ọrọ naa ko ba ofin ileeṣẹ awọn mu.
Amọ ijọba apapọ fesi pe igbesẹ awọn lati fofin de Twitter ni Naijiria ko ni nnkan lati ṣe pẹlu bi Twitter ṣe fa ọrọ Aarẹ yọ lori ikanni naa.
Lẹyinorẹyin, ọpọ awọn ọmọ Najjiria lo n gba ọna ẹyin wọle sori ikanni Twitter pẹlu iranlọwọ "VPN."
Nigba ti awọn kan ninu ijọba Buhari n lo Twitter lasiko ti wọn ba tẹkọ leti lọ si orilẹ-ede mii.