NDLEA bá igba Tramadol àti Igbó kílò kan àbọ̀ lọ́wọ́ aláwàdà ayélujára De-General

Aworan adẹrinposonu De General

Oríṣun àwòrán, NDLEA

Àwọn òṣìṣẹ́ àjọ tó ń gbógun ti egbògi olóró NDLEA, fi panpẹ òfin gbé adẹ́rìnpòṣónú kan lórí ayélujára Sunday Joshua, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí De-General.

Nígbà tí àwọn ẹ̀ṣọ́ àjọ náà ṣe abẹwo sí oríta kan ni Orchid Estate ní agbègbè Lekki ní ìlú Èkó, ni wọ́n nawọ́ gán De-General àti àwọn mẹ́ta mìíràn.

Ìròyìn ní igba sáṣẹ́ẹ̀tì Tramadol oní mìlígíràmù márùndínlọ́tàlénígba àti kílógíràmù kan àbọ̀ igbó ni wọ́n bá lọ́wọ́ wọn.

Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ adarí eto ìròyìn àti ìpolongo àjọ NDLEA, Femi Babafemi ní nígbà tí àwọn òṣìṣẹ́ àwọn ń ṣe ìwọ́de ni àwọn afurasí náà na pápá bora, tí wọ́n sì sá wọ ojúlé keji, opopona Akinlolu, ni Orchid Estate tó jẹ́ ilé De-General.

Ó fi kún pé nígbà tí wọ́n ṣe àyẹ̀wò ilé alawada ayelujara naa, ní wọn bá àwọn egbògi olóró nínú ilé ẹni ọdún méjìlélógún naa.

Aworan atẹjade lati ọdọ NDLEA

Oríṣun àwòrán, NDLEA

Babafemi ní fọ́nrán tó gba orí ẹ̀rọ ayélujára kan jẹ́ èyí tí Joshua ṣe láti fi dènà àwọn ẹ̀ṣọ́ NDLEA láti ṣe àyẹ̀wò ilé rẹ̀.

Ní òwúrọ̀ ọjọru ni Dé-General ti kọ́kọ́ ké gbàjarè pé àwọn ẹ̀ṣọ́ NDLEA yabo ilé òun loju opo ayélujára Instagram rẹ, eyi tó ti ń fà awuyewuye láàárín àwọn olólùfẹ́ rẹ̀.