Adebayo Alao Akala life and times: Wo àwọn ǹkan tí ó yẹ kí o mọ̀ nípa Alao Akala ìlúmọ̀ọ́ka olóṣèlú tó dágbére fáyé

Aworan Alao Akala

Oríṣun àwòrán, Facebook/Otunba Adebayo Alao Akala

Ninu awọn oloṣelu nipinlẹ Oyo, Adebayo Christopher Alao Akala jẹ agbaọjẹ oloṣelu.

Ni ilu abinibi rẹ tii ṣe Ogbomosho, pupọ lo nifẹ rẹ ti wọn a si maa ṣafiwe rẹ gẹgẹ bi Ladoke Akintola ode oni.

O ṣeni laanu pe agba oloṣelu yii dagbere faye to si ki duniyan pe o digba kan naa.

Ọpọ ni yoo maa ṣe iranti Alao Akala fawọn ipa ribi ribi to ko lagbo oṣelu bo tilẹ jẹ pe awọn iṣẹlẹ kan waye loṣelu naa to ṣebi ẹni ta epo si aṣọ aala rẹ.

Àkọlé fídíò, Mo mọ èsì ọ̀rọ̀ kẹ̀, Queen Salawa Abeni ló kọ́kọ́ ta sí mi pé èmi 'Alaragbo ọmọ bàbá olójú kan' ní 1980s - Kuburat Alaragbo

Gomina to wa lori alefa bayi Seyi Makinde ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi ẹgbọn, ọrẹ ati oluọmọ ipinlẹ Oyo.

Makinde ti kede pe ki wọn mu asia ilẹ yi walẹ ni iranti Akala.

O tẹsiwaju pe o jẹ Gomina kan to gbe idagbasoke kaakiri gbogbo origun ipinlẹ Oyo

Ni tiwa ni BBC Yoruba, a gbiyanju lati ṣe agbeyẹwo igbe aye rẹ ati awọn nkan ti ọpọ ko mọ nipa Alao Akala.

Amin iyasọtọ kan

Ọjọ Kẹta, Osu Kẹfa, ọdun 1950 ni wọn bi gbajugbaja oloselu, Christopher Adebayo Alao-Akala.

Alao-Akala lọ si ile iwe Government Technical College, Tamale, Ghana ati Ogbomoso High School, Ogbomoso.

Nigba to pari nibẹ, o tẹsiwaju lọ si ile iwe giga fasiti ti ilu Ibadan.

Lẹyin naa lo bẹrẹ isẹ ọlọpaa titi to fi gba oye ADC si Ọga Agba Ọlọpaa lorilẹede Naijiria.

Àkọlé fídíò, BBC Gov Debates: Ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ni àwọn olùdíje yóò ṣe

Nkan meje mii to yẹ ko o mọ nipa Alao-Akala ti Ọyọ

  • Alao-Akala ni gomina tẹlẹri ni ipinlẹ Ọyọ lati ọdun 2007 si ọdun 2011 labẹ ẹgbẹ oselu PDP.
  • Oloye Alao-Akala bẹrẹ oselu gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ New Dimension, lẹyin naa o darapọ mọ ẹgbẹ UNP, ko to di wi pe o jẹ Alaga Ijọba ibilẹ Ariwa Ogbomoso ni ẹgbẹ oselu APP ni ọdun 1999 si 2002.
  • Alao-Akala lo da ẹgbẹ Ogbomoso Unity Forum to darapọ mọ ẹgbẹ oselu PDP.
  • Ọdun 2014 ni Alao-Akala kuro ni ẹgbẹ oselu PDP lọ si Labour Party nibi to ti dije dupo gomina ninu idibo gbogboogbo ti ọdun 2015.
  • Ọjọ Kẹrindinlogun, ọdun 2017 lo yapa kurọ ni ẹgbẹ oselu Labour Party lọ si ẹgbẹ oselu APC pẹlu ayẹyẹ nla.
  • Lẹyin idibo abẹlẹ ẹgbẹ oselu APC ti o ni kọnu-kọhọ ninu , Alao-Akala fi ẹgbẹ oselu APC silẹ lọ si ADP lati le dije dupo gomina ninu idibo ti yoo waye lọdun 2019.
Alao Akala

Oríṣun àwòrán, Google

Àkọlé àwòrán, Gomina tẹ́lẹ̀rí ní ìpínlẹ̀ Ọyo, Alao Akala ń díje dupò gomina lábẹ́ ẹgbẹ́ òsèlú Action Democratic Party (ADP).
Àkọlé fídíò, 'Mo sọ fún Dókítà pé èmi ò lè gé ọyàn mi, pé ṣọ́ọ̀ṣì yóò fi àdúrà ṣẹ́gun àìsàn jẹjẹrẹ ọmú mi'