Adebayo Alao-Akala: 'Mo ti dàgbà ọ̀jẹ̀, n kò ní díje fún ipò gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo mọ́'

Otunba Christopher Adebayo Alao-Akala

Oríṣun àwòrán, Facebook/Otunba Adebayo Alao-Akala

Gomina ana ipinlẹ Oyo, Otunba Christopher Adebayo Alao-Akala ti kede pe oun ko ni dije fun ipo gomina ipinlẹ naa mọ nibi ti oun ba a de bayii.

Otunba Akala sọrọ yii lori eto kan to waye ni ileeṣẹ redio kan niluu Ibadan lọjọ Abamẹta, ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kẹjọ ọdun 2020 yii.

Bakan naa o fidi ọrọ naa mulẹ fun BBC Yoruba latẹnu agbẹnusọ rẹ, Yusuf Olaniyi pe oun ti fiṣẹ silẹ fawọn to ṣẹṣẹ n dide ninu oṣelu.

Akala ni ohun ti o ku f'oun lati ṣe bayii ni lati rii pe oludije to kun oju oṣuwọn jade ninu ibo abẹle lati ṣoju ẹgbẹ oṣelu APC ninu ibo gomina ọdun 2023 to n bọ.

Otunba Alao-Akala to ṣe ọjọ ibi aadọrin ọdun loke eepẹ laipẹ yii ni igbesẹ oun lati ma dije fun ipo gomina mọ yoo f'oun lanfaani lati ṣiṣẹ ipẹtu si aawọ ti gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ, oloogbe Abiola Ajimobi gbe le oun lọwọ daadaa.

Alao-Akala ni oun ati Ajimọbi sọ ọpọlọpọ ọrọ ninu eyi tawọn ti fẹnu ko pe ki oun pari aawọ to wa laarin gbogbo ọmọ ẹgbẹ to n binu lẹyin idibo gbogbogbo to lọ.

O ni oun ti ba gbogbo awọn ọmọ APC to n binu atawọn to ti kuro sọrọ, wọn si ti gba lati pada sinu ẹgbẹ.

Gomina Oyo tẹlẹ ni oun rawọ ẹbẹ si awọn mii pe ki wọn j'eburẹ ki wọn to gba lati pada sinu ẹgbẹ.

Otunba Christopher Adebayo Alao-Akala

Oríṣun àwòrán, Facebook/Otuba Adebayo Alao-Akala

''Ko si ohun ti n ko mọ nipa oṣelu ipinlẹ Oyo, n o si ni erongba lati fa ẹnikan kalẹ lati dije fun ipo gomina lọdun 2023,'' Alao-Akala lo sọ bẹẹ.

Alao-Akala sọ pe ilẹkun ile oun ṣi silẹ fun gbogbo ọmọ ẹgbẹ APC nipinlẹ bayii.

Nigba ti o n kin ọrọ Akala lẹyin, oluranlọwọ fun gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ, Yusuf Olaniyi sọ fun BBC Yoruba pe Alao-Akala ti di agbaọjẹ ninu oṣelu ipinlẹ, iyẹn lo ṣe ni oun ko ni dije fun ipo gomina mọ.

O ni Akala ti da oun to fẹ da laye papaa julọ lagbo oṣelu, ''eyi gan lo jẹ ko pinnu lati fun awọn to wa lẹyin ninu ẹgbẹ lati dije.''

O ni Alao-Akala ti jẹ oye lemọmu bayii, ko tun le maa du oye Ṣeriki mọ, nitori oun ni alaga apẹtu si aawọ ninu ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ, ko le maa du ipo gomina mọ to jẹ Ṣeriki.

Bi o lo dagba, bi o loo gbo, bo ba pẹ titi, oju a hun jọ, Olaniyi ni agba naa ti de si Otunba.