Mò kabamọ́ ìṣẹlẹ tó wáyé láàárín èmi àti Agbowu,màá tẹlé àṣẹ lọ rọọ́kún nílé-Oluwo

Aworan Oluwo ilu Iwo

Oríṣun àwòrán, Instagram/Telu1

Eti to ba gbọ alọ ni ọrọ yii,ko ni da ki o ma gbọ abọ.

Oluwo ilu Iwo Oba Abdulrasheed Adewale Akanbi ni oun kabamọ iṣlẹ to waye laarin oun ati Agbowu ilu Ogbaagbaa .

Tori naa, oun bọwọ fun aṣẹ igbimọ lọbalọba to ni ki oun lọ rọkun nile fun igba diẹ.

Inu atẹjade kan ti Oluwo fi ranṣẹ si BBC Yoruba ni ọrọ yi ti jade.

Ọba Abdulrasheed ni toun ti pe idajọ lọ rọọkun nile naa fẹ lagbara diẹ ṣugbọn oun yoo bọwọ fawọn to pa aṣẹ naa.

O fi kun ọrọ rẹ pe oun ko fi igba kankan ṣiwọ lu Ọba Agbowu tabi ọba kankan ati pe oun kun fun imoore awọn to n dari lọbalọba ilẹ Yoruba labẹ aṣẹ Oni Ile Ifẹ Oba Babatunde Enitan Ogunwusi.

Ṣaaju asiko yi Oluwo ti fariga pe awọn lọbalọba ko laṣẹ lati ni ki oun lọ rọọkun nile.

Ni bayi ti o ti gba idajọ naa, ko ni laanfaani lati kopa ninu ipade awọn lọbalọba fun oṣu mẹfa gbako.

Elédùmarè ló rán mi sí gbogbo Ọba Yorùbá - Oluwo

Kabiyesi Oluwo ilẹ̀ iwo, Ọba AbdulRaheed Adewale Akanbi ti ke gbajare pé gbogbo ìṣòro Ilẹ́ Yorùbá ko ṣe lẹ́yìn ìwà àwọn lọ́balọ́ba ilẹ̀ Yoruba.

Ọba Abdulrasheed sọ èyi di mímọ nínú fọ́nran kan to ṣe sita loni ọjọ aje láti sọ idí ti ó fi máa n gbe ìgbésẹ̀ ti òun máà ń gbé àti ìhà ti ó ń kọ si ìṣẹ̀lẹ̀ láwùjọ.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ, Oluwo ni Olodumare lo rán òun wá sórí ìtẹ láti wá tún Orí ìtẹ Ọba ṣe to si fí àṣẹ "Kabi ọ ò sí" lée láti maa sọ òòtọ fún gbogbo Ọba.

Àkọlé fídíò, Oluwo ilu Iwo ba BBC Yoruba sọrọ lori awuyewuye pẹlu awọn Ọba

"Ọlọrun ni kí n lọ sọ pe òun ń bọ̀ ṣùgbọ́n ki n lọ fọ ààfin òun mọ". Awa ti a n pe ara wa lọ́ba lórilẹ̀ aye kọ́ lọ́ba, Ọlọrun gan lọba, a kan n róle fun Ọba ni".

Kabiesi ni ìwásáye àwọn Ọba òde oni láti ṣe atúnṣe ǹkan ti àwọn baba nla to lọ ti ṣe, lati ṣe àtunṣe àwọn ǹkan mìíran ti wọ́n ti ṣe sẹ́yìn.

Njẹ o yẹ ki Ọba Alade maa bọ oriṣa

Kabiyesi Oluwo ni àrifin àti abuku ń ba ilé Babanla ilẹ̀ Yoruba jẹ́, eyi ti o fi ilú ilé-Ifẹ se ìbùgbe, nítori àwọn kùdiẹ̀-kudiẹ̀ kan ń ṣẹlẹ.

Oluwo ni Ori ni o yẹ ki Ọba maa bọ kii ṣe Orisa, nítori Ọba to n role fun Oodua to tun wá n bọ oriṣa, àwọn ti kò to o gan wọ́n o sọ pe àwọn jù ú lọ.

O ní gbogbo àwọn orisa Sango, Ògun, kéré si òòdua ti Ọba yoruba ń ṣoju fún, nítori náà àwọn Ọba atijọ ti wọ́n ń bọ òrìsà, ìgbà aimọ ni.

Kabíyesi ni eyi jẹ́ iṣẹ́ ti Olodumare ran òun ni pe àwọ́n ti wọ́n gbé ade Oodua sori kò gbọ̀dọ bọ orisa kankan.

O ní Ori lo tobi ju nínú Ifa, Ọba kìí ṣe ẹgbẹ́ Orisa nítori náà kò tọ̀na láti maa bọ oriṣa nítori ènìyàn gan ju oríṣà lọ.

O yẹ kí gbogbo Ọba Alade fi òrìṣà silẹ̀ fún ará ìlú, Ọba to ba ti gbe Ade sori ko gbọdọ bọ oriṣa.

Kìí ṣe Gbogbo ọmọ Yoruba ni Oodua bí

Kìí ṣe gbogbo ọmọ Yoruba ni Oodua bí o, ṣùgbọ́n òun lo kọ́kọ́ mu Ade wa, ìjọba tuntun ni Oodua mu wa, ti o si ti yan awon ti wọ́n yoo jọ se ìjọba, ìgba náà ni ọba bẹ̀rẹ̀ si ni yan, Balogun , ọtun Oba, àti oníruuru ìjọye to n ba ọba jiroro.

"Gẹ́gẹ́ bi Oluwo, Ọmọ Oodua tààrà ni mi", Iya mi ni wọ́n n pe ni "Luwo Gbagida, baba to bi Luwo Gbagida Ọọni Ogun ló jáde níbẹ, Baba to bi iya mi ni Ọta-aata, Owodo bi Ọta-aata, nígbà ti Owodo jẹ ọmọ Alade ju òògun lọ ti wọ́n ń pè ni Ladejogun, ni ọmọ-ọmọ Lajamisan ti lajamisan fi jẹ ọmọ-Ọmọ Oranmiyan titi to fi kan Oodua.

Ọyọ ko ju Ifẹ lọ tori ti Ọyọ ba ju Ifẹ lọ ni Ọ̀ramiyan ko ni kúro ni Ọjọ ko tun lọ gba Ade ni Ifẹ, nígbà ti o de bẹ, o mu ẹjẹ Odudua pada.

Ọba ni ojiji Ọlọrun Ọba lórilẹ̀ ayé nítori náà ko yẹ ki Ọba maa bọ oriṣà

Àkọlé fídíò, Kò sí ǹkan tó ń jẹ́ ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ tàbí ìmọ̀le nínú àgbékalẹ̀ Amotekun - Alake ti Egba