Oluwo: Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ láwọn aṣíwájú orílẹ̀èdè Nàìjíríà ti fi ìwà àjẹbánu àti ìjẹkújẹ lé dànù sí òkè òkun

Oríṣun àwòrán, oluwo of iwo
Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi ni lootọ loun sa kuro lorilẹede Naijiria lọpọ ọdun, ṣugbọn iwa ijẹkujẹ to gogo lorilẹede Naijiria lo sọ oun di alarinkiri ni ilẹ okeere.
Oluwo ti ilu Iwo ni ko si idi meji ti ọpọ awọn ọdọ fi n digba di agbsn wọn gba oke okun lọ bikoṣe iwa ajẹbanu to gogo laarin awsn to di ipo oslu ati iṣejọba mu lorilẹede Naijiria.
- Ìtàn ìgbésí ayé Oshodi, ọmọ Tápà léǹpe tó di akọni ní ìlú Eko
- Inú jìn! Akitiyan ọmọ'ṣẹ́ mi tó wà lára àwọn tó jí ìbejì mi gbé kò kéré nígbà tí á n wá wọn- Akeugbagold
- Wo ìgbà márùn ún tí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ ti gé ẹ̀mí ọgá wọn kúrú
- Àgbo Madagascar ti wà ní Nàìjíríà ṣùgbọ́n kìí ṣe ọ̀fẹ́, a ní láti sanwó-Mínísítà
Ọbalaye naa sọ eyi lasiko to fi n gba alejo kọmiṣọna feto Ẹkọ ni ipinlẹ Ọṣun, Ọgbẹni Ọlayinka Ọladoyin Fọlọrunshọ ati igbimọ rẹ ti wọn wa ṣe abẹwo si ibudo ileẹkọ giga fun ẹkọṣẹ olukọ apapọ ni ilu Iwo.
Kabiyesi Oluwo ni oun ni lati fi orilẹede Naijiria silẹ lọpọlọpọ ọdun sẹyin lati wa papa oko tutu fun ọjọ ọla oun nitori iwa ijẹkujẹ ati ajẹbanu to n waye laarin awsn atuks ijọba orilẹede Naijiria nigba naa.
Gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ ilu Canada ni kabiyesi Oluwo wa nigba ti ipe ati wa gun ori apere awsn babanla rẹ jade sii lọdun mẹrin sẹyin.
Oluwo: Ó dàbí ẹni pé ọ̀tá pọ̀ fún mi, inú wọn kò dùn sí bí mo ṣe ń ṣakọ
Oluwo tilẹ Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi ti fesi lori ipinnu igbimọ lọbalọba nipinlẹ Ọsun to ni ko lọ rọọkun nile fun osu mẹfa.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Oluwo ni lootọ ni awọn se ipade lọbalọba lootọ ti Ọọni ko si ni asẹ lati ni ki oun lọ rọọkun nile na.
O ni gomina ipinlẹ Ọsun nikan lo ni asẹ lati ni ki oun lọ rọọkun nile na, to si dabi ẹnipe wọn ti ni nkan ninu si oun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Elédùmarè ló rán mi sí gbogbo Ọba Yorùbá - Oluwo
- Toyin Abraham ọkọ rẹ̀ àti Ire ní London, Odunlade 'kòlábò' pẹ̀lú Mercy Aigbe
- Èlé owó iná ọba kọ́ ló kàn, ẹ kọ́ ṣàtúnṣe sí ìlànà àdánú tẹ́ ń ṣe fún wa - Iléeṣẹ́ apínná sọ fún ìjọba
- Àdínkù bá owó ojúmọ́ ọlọ́kadà l‘Ọyọ láti ₦200 si ₦100, owó gbígbà bẹ̀rẹ̀ lónìí
- A fẹ́ ìtọ́jú fún Boko Haram tó bá ronúpìwàdà, ẹ dá iléeṣẹ́ sílẹ̀ fún ìtọ́jú wọn - Ilé aṣòfin
- Olùkọ́ tó fi tipá gba ìbálé akẹ́kọ̀ọ́ tó fẹ́ wọ fásitì rí ẹ̀wọ̀n ọdún 21 he
- Fayose, o kò ní àmúyẹ gidi láti di ọmọ ẹgbẹ́ wa, àyè kò sí fún ọ - APC Ekiti
"O dabi ẹni pe inu wọn ko dun bi mo se maa n sakọ, ti wọn si n binu mi. Gbogbo wọn ni wọn kan oro mi sinu, o si dabi ẹni pe ọta pọ, Ọlọrun yoo si gbe mi jẹri wọn."

Oríṣun àwòrán, Instagram
Nigba to n sọrọ lori bi wọn se ni o yaju si Alaafin ati Ọọni, Oluwo ni oun ko gba ade ni Ọyọ, oun si ni oun lasẹ lati fi ọba miran jẹ nilẹ Iwo, kii se Alaafin, gẹgẹ bo se waye ni Ikoyi.

Oríṣun àwòrán, Oluwo
"Ile ifẹ ni mo ti gbade lọdọ iya mi, tori ọmọ alade ni mi nile Ifẹ, emi ko gba ade ni Ọyọ, ipinlẹ Ọyọ ni Alaafin wa, ko si lee maa gbe ade le Onikoyi to wa labẹ mi lori. Alaafin sọrọ si mi tori pe n ko jẹ ko gbe ade le Onikoyi lori, amọ ibi to ba kan onikaluku ni ko duro si bii ọba."
Oluwo ni oun si ni Ọba alade nilẹ Iwo, Oluwo ti Iwo, Alase lori orisa, ọba miran ko si lee ni ki oun lọ rọọkun nile na, wọn kan le ni ki oun ma wa si ipade wọn mọ ni.
Ìgbìmọ̀ lọ́balọ́ba l'Ọ́sun ní kí Oluwo lọ rọ́ọ́kún nílé fún oṣù mẹ́fà
Iroyin to n tẹ wa lọwọ ti kede pe igbimọ lọbalọba nipinlẹ Ọsun ti ni ki Oluwo tilu Iwo, Aba Abdulrasheed Akanbi lọ rọọkun nile fun osu mẹfa gbako.

Oríṣun àwòrán, Oluwo
Igbimọ kan ti igbimọ lọbalọba naa gbe kalẹ, eyi ti Ọrangun ile Ila, Ọba Wahab Adedọtun ko sodi, lati sewadi awọn isẹlẹ to nii se pẹlu Oluwo, gbe abọ wọn kalẹ lọjọ Ẹti.
- Ìjọba Ọ́ṣun, Oluwo kò yẹ lẹ́ni tó leè darí ìlú, ẹ bá wa le kúrò lórí ìtẹ́ - Olú ti Ilé-Ogbó
- Ija eerin meji: Oluwo ati Ọọni
- Ani sẹ, Ọọni ran alaabo rẹ simi - Oluwo
- Ìgbà mẹ́rin tí ọ̀rọ̀ Oluwo dá awuyewuye sílẹ̀
- Ọ̀rọ̀ èmi àti Olorì Chanel Chin kò yé ara wa mọ́ nínú ilé- Oluwo
- Ìwà ọ̀dàlẹ̀ ni bí ẹ kò bá gbé iléèwé ìkọ́ṣẹ́ olùkọ́ni kalẹ̀ sí ìlú Ìwó- Oluwo
- Àwọn ọba tó wà lábẹ́ mi ń talẹ̀ nítàkutà- Oluwo
- Ìjọba Ọṣun ti dásí ìjà láàrin Oluwo àti Agbowu
Lẹyin abọ igbimọ naa, ni igbimọ lọbalọba ọhun ba pe ipade pajawiri, eyi to waye nibujoko ijọba ipinlẹ Ọsun to wa ni Abẹrẹ.
Ipade naa, ti Ọọni tilu Ile Ifẹ, Ọba Adeyeye Ẹnitan Ogunwusi lewaju rẹ, wa fohun sọkan pe ki Oluwo lọ rọọkun nile na fun osu mẹfa.

Oríṣun àwòrán, Ọba Dikrulahi Ọlaleke Akinrọpo, Ọlabiran Kẹta.
Igbesẹ yii si lo waye lẹyin ọsẹ kan pere ti Oluwo lu Agbowu tilu Ọgbaagba nibi ipade alaafia kan ti igbakeji sga agba ọlspa pe nilu Osogbo.
Nigba to n bawọn akọroyin sọrọ lẹyin ipade pajawiri naa, Ọrangun Ile Ila ni asẹ ti igbimọ naa pa pe ki Oluwo lọ rọọkun nile na ko ni ohunkohun se pẹlu ija to waye laarin rẹ ati Oluwo.
Amọ o ni wọn se ipinnu ọhun lẹyin iwadi wọn nipa isesi Oluwo si awọn ọba alaye yoku nilẹ Yoruba.

Oríṣun àwòrán, Oluwo
Ọrangun ni Oluwo ti yaju tẹlẹ si Alaafin tilu Ọyọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyemi Kẹta ati Ọọni tilu Ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi.

























