Boko Haram: CAN àti àwọn ará Chibok ní kò sí orílẹ̀èdè tó yege nínú yíyí ọkàn aṣẹ̀rùbálú padà

Oríṣun àwòrán, @ElvisChinedu12
Ile igbimọ aṣofin nilu Abuja ti gunle abadofin ti yoo ṣedasilẹ ileeṣẹ ijọba, ti yoo ma ṣetọju awọn ọmọ ẹgbẹ Boko Haram to ba ronupiwada.
Abadofin ọhun ni Sẹnatọ to n ṣoju Ila-oorun ipinlẹ Yobe, to tun jẹ gomina ana nipinlẹ ọhun, Ibrahim Gaidam n ṣagbatẹru rẹ.
Gẹgẹ bi agbekalẹ abadofin naa ṣe sọ, ileeṣẹ ọhun yoo pese anfani fun awọn agbesunmọmi to ba jọwọ ohun ija wọn, lati lọ si ile iwe.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Olùkọ́ tó fi tipá gba ìbálé akẹ́kọ̀ọ́ tó fẹ́ wọ fásitì rí ẹ̀wọ̀n ọdún 21 he
- Fayose, o kò ní àmúyẹ gidi láti di ọmọ ẹgbẹ́ wa, àyè kò sí fún ọ - APC Ekiti
- Maryam Sanda pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lóri ìdàjọ́ ikú
- ''Láìpẹ́, ìjọba ìpínlẹ̀ Eko yóò fi ǹkan tó dára míì rọ́pò Kẹ̀kẹ́ àti ọ̀kadà''
- Ìhàlẹ̀ lásán ní NURTW ń ṣe torí pé a dínà owó tí wọn ń kó sápò - Ìjọba Ọyọ
Lẹyin eyi, yoo ṣe atunkọ ohun ti wọn gbagbọ, iyipada ọkan wọn, ti yoo si tun da awọn eeyan naa pada si awujọ gẹgẹ bi ẹni to ti ni iyipada ọkan ati ẹdun tuntun.
Ko tan sibẹ, ileeṣẹ naa yoo tun kọ awọn eeyan naa ni iṣẹ ọwọ bii gbẹnagbẹna, iṣe amọkoko, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Igbimọ to ga julọ fun ọrọ ẹsin Musulumi, eyi ni Supreme Council for Islamic Affairs ti ṣe atilẹyin fun abadofin naa.

Oríṣun àwòrán, @thesignalng
Ṣugbọn lẹyin wakati diẹ ti abadofin naa kọja kika akọkọ, ni awọn olugbe ilu Chibok, ti Boko Haram ṣakọlu si lọdun 2014 ati CAN tako abadofin naa.
Bẹẹ naa ni adari ajọ ọmọlẹyin Kristi, CAN lori ọrọ ofin, Kwamkar Samuel sọ fun awọn akọroyin pe, oun ko tii ri orilẹ-ede kankan lagbaye to ṣaṣeyọri ninu yiyi ọkan ẹgbẹ aṣẹrubalu pada.
Yatọ si ẹgbẹ CAN ati awọn ara ilu Chibok, ogunlọgọ awọn Naijiria lo n bu ẹnu ẹtẹ lu awọn asofin naa pe, abadofin ọhun kii ṣe ọna abayọ si ọrọ ikọ Boko Haram.
- Ṣé òògùn Chloroquine lè dènà ààrùn Coronavirus bí?
- Lekan Balogun, dá ₦6.5m owó oyè tó gbà lọ́wọ́ òkú padà, àwọn ará ilé rẹ̀ ń bèèrè - Olúbàdàn
- Kìí ṣe torí gbígba àmì ẹ̀yẹ ni ọmọ wa ṣe kú, a dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọba tẹ rántí rẹ̀ - Ẹbí Adadevoh
- Kò síbi tó dàbí ilé, tìlù-tìfọn ni wọ́n fi kí Anthony Joshua tó bẹ ìlú rẹ̀, Ṣágámù wò káàbọ̀
Agbẹnusọ fun ilu Chibok ni tirẹ sọ pe, abadofin ọhun jẹ ohun ti ko ni ọgbọn ninu.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kẹrinla Oṣu Kẹrin ọdun 2014 ni ikọ Boko Haram ṣakọlu si ilu Chibok, to si ji awọn ọdọbinrin to le ni igba gbe lọ.














