Royal Tussle: Olúbàdàn ní Lekan Balogun nìkan ló ń bá òun jà, àwọn ìjòyè yókù kò sí lẹ́yìn rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Others
Kaka ki ewe agbọn dẹ, ko ko ko lo n le si lọrọ aawọn to wa laarin Olubadan ati awọn ijoye rẹ mọkanlelogun, ti wọn ti di ọba bayii.
Olubadan tilẹ Ibadan, Oba Saliu Adetunji Aje Ogungunnisọ kinni, ti naka aleebu sawọn ijoye rẹ lori bi wọn se n lo awọn ẹsun ti ko lẹsẹ nlẹ lati fi ba oun lorukọ jẹ, ti wọn si tun n tẹnbẹlu ori apeere toun wa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Oyè Ibadan kò sí fún títà - Otun Olubadan, Lekan Balogun
- Owó àwọn aṣòfin kò pọ̀jù, iṣẹ́ kàbàtì tí wọn ń ṣe ju owó oṣù wọn lọ - Buhari
- Kò síbi tó dàbí ilé, tìlù-tìfọn ni wọ́n fi kí Anthony Joshua tó bẹ ìlú rẹ̀, Ṣágámù wò káàbọ̀
- Àbòsí ló wà níbẹ̀ tí ìpínlẹ̀ Eko ò bá ṣe Amotekun- Bode George
- BBC Yorùbá pé ọdún méjì! Ẹ wò wá ẹ wo iṣẹ́ ọwọ́ wa
Atẹjade kan to bọ sọwọ awọn akọroyin lati aafin Olubadan wa n fewe ọmọ mọ awọn araalu leti pe ki wọn yago gede gede fun awọn iroyin ẹlẹjẹ, eyi to fara pẹ ọrọ ahesọ nile ọti ati eyi to jọ tawọn eeyan ti oogun oloro n da laamu, to lu igboro pa bayii.
Atẹjade naa, eyi to n fesi si iwe kan tawọn ọba mọkanlelogun ọhun fisita lọjọ Aje pe ọgbọn miliọnu naira ni Olubadan n ta oye nilẹ Ibadan, wa n leri leka pe Olubadan ti pinnu lati wẹ ara rẹ mọ lọwọ awọn ọrọ abanilorukọjẹ bii eyi.

Oríṣun àwòrán, Others
Atẹjade naa, ti amugbalẹgbẹ Olubadan feto iroyin, Adeola Oloko fisita, wa n kesi awọn ijoye Olubadan ọhun lati tọkasi eeyan kan pere, to ra oye nilẹ Ibadan pẹlu ọgbọn miliọnu naira.
"Ko ba dara ki wọn tu asiri ibi ti wọn ti san owo naa ati akoko ti wọn san, se banki ni wọn san si ni abi sọwedowo ni wọn fi san tabi wọn fi sọwọ lati ori asunwọn owo kan si omiran? Se owo ilẹ okeere ni owo ọhun ni abi Naira ilẹ wa, ati pe iru oye wo ni onitọun fẹ ki Olubadan fi oun jẹ, to fi n san ieu owo banta banta naa."

Oríṣun àwòrán, Others
Atẹjade naa fikun pe, "Ọtun Olubadan, Oloye Lekan Balogun to fẹsun kan ọba alade ọhun lo kuna lati jẹ ki awọn araalu mọ nipa owo oye ti Olubadan gba nigba tawọn agba ijoye wa n dirẹbẹ niwaju ọba naa pe ko di awọn alafo to wa ninu igun oye ilẹ Ibadan lati ori Ọtun Olubadan titi de Jagun."
O ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira pere ti Olubadan maa n gba naa lo gba amọ ti akasọ oye meji ba wa niwaju ẹnito fẹ joye, a jẹ pe ẹgbẹrun lọna igba naira ni onitọun yoo san, to ba si jẹ alafo oye mẹta ni, a jẹ pe ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira ni yoo san.

Oríṣun àwòrán, Others
"Owo yii la maa n san si apo asunwọn igbimọ Olubadan, eyi ti wọn yoo pin si ọna mẹta. Igun kan yoo lọ sọdọ Olubadan, ti igun oye ỌTUN ATI Balogun Olubadan yoo si pin meji to ku."
"Bi awọn ijoye se n parọ kiri naa ree lasiko ti Olubadan fi Ajimobi ati aya rẹ joye, ti wọn ni miliọnu lọna aadọta naira ni Olubadan gba lọwọ gomina ana naa, ayafi igba ti onitọun tan imọlẹ si ọrọ naa pe oun ko san kọbọ fun oye ti wọn fi oun jẹ ọhun.

Oríṣun àwòrán, Others
"Ti eeyan ba jẹ ọba lẹnu ọdun mọkanle laadọrun bii Olubadan, iru ọrọ aye wo lo tun ku ti yoo maa ko jọ? Iwa Oloye Lekan si dabi iwa asa, to ro pe gbogbo ẹda yoku naa n jẹ oromọdiẹ. A si fẹ ki Lekan Balogun wa salaye miliọnu mẹfa ati aabọ naira to gba lọwọ Ọmọwe Sunday Ọladiti to ti di oloogbe bayi, lọdun 2017, lori ẹtanjẹ pe oun yoo ba gba oye Jagun lọwọ Olubadan?"
"Lẹyin ti ọkunrin naa ku, Lekan Balogun ko da owo naa pada nitori iyawo ati awọn ọmọ oloogbe ti tọ Olubadan wa pe ko ba awọn dasi ọrọ yii, ki awọn lee ri owo gba pada. Koda, tori atilẹyin owo ti gomina tẹlẹ, Rashidi Ladọja se fun Lekan Balogun laipẹ yii, lo se gbe ẹjọ to pe kuro nile ẹjọ laipẹ yii, to ba si dabi irọ, ẹ bi ajọ EFCC ati ileesẹ ọlọpa nilu Ibadan."
Atẹjade naa tun salaye pe danfo ni Lekan Balogun wa ninu ija to n ba Olubadan ja, ko ni ọmọ ogun lẹyin rara nitori oun naa lo n buwọlu iwe lori awọn oloye yoku, bẹẹ si ni losu kejila ọdun 2019 to kọja ni Lekan Balogun ati awọn oloye yoku wa bẹbẹ fun idarijin lọdọ Olubadan tori bi wọn se fi Baalẹ Alape jẹ lai lọwọ Olubadan ninu.













