Afurasí tó gbé oògùn olóró lọ sílé ìjọsìn ní ọwọ́ NDLEA bá tẹ̀ẹ́ kó tó ké Hallelujah

Oríṣun àwòrán, others
Ọwọ palaba afurasi agboogun oloro kan ti segi ni ile ijọsin kan nilu Eko.
Afurasi to n ṣowo nọbi cocaine ati heroin yi la gbọ pe wọn ti n wa tẹlẹ lori ẹsun pe o gbiyanju ati gboogun oloro lọ si ilu ọba.
Awọn oṣiṣẹ ajọ to n gbogun ti oogun oloro NDLEA lo tọ ipasẹ arakunrin Stephen Afam Ikeanyionwu lọ si ile ijọsin ilumọọkan kan nibi ti wọn ti gba mu ni kete to wọ sọọsi.
Adugbo Mike Ajari ni Ojodu Berger ni ile ijọsin naa wa.
- Tinubu, fi ipò Ààrẹ sílẹ̀ fún àwa ọmọ rẹ kí o lè lọ sinmi- Yahaya Bello
- Ìtàn ayé Ọba Seriki Abass ti Badagry, tó ní aya 128, ọmọ 144
- Àwọn jàndùkú afẹ̀mí-ṣòfò ṣekúpa èèyàn 24 ní Kaduna àti Katsina lọ́jọ́ kan ṣoṣo
- Arteta ta Pàù! Lukaku lagi mọ́ Arsenal lórí láti gbayì fún Chelsea
- Ọmọ ọdún márùn-ún tó jẹ́ ògbóntagí èdè Yorùbá, Adigun Olowe jẹ oyè nílùú Eko
A gbọ pe wọn mu lẹyin tawọn agbofinro da oogun oloro to to iwọn kiligiramu 69.65kg lọna ki wọn to ribi gbe lọ si ilu ọba lỌjọbọ tii ṣe ọjọ Kejila, oṣu Kẹjọ, 2021.
Ẹru ti oogun oloro yi wa ni wọn ti ṣaaju fi ranṣẹ gba tọwọ ileeṣẹ to n ko ẹru tawọn naa si gbe fun awakọ lati gbe lọ si aaye ikẹrusi ni papakọ ofurufu.
Lẹyin ti ọwọ tẹ awakọ to gbe ẹru naa lọ, iwadii waye nibi ti wọn ti tu asiri ẹni to ni ẹru gangan.
Ko pẹ si igba naa ni awọn agbofinro dẹ ọdẹ Stephen Afam Ikeanyionwu ti wọn si ri mu ni ile ijọsin ki o to le sọ pe oun ke Halleluyah.
Bakan naa ni papakọ ofurufu Murtala Muhammaed nilu Eko yi, omi tẹyin wọ igbin arakunrin mii Abibu Miminu, lẹnu nigba ti wọn ni ko bẹrẹ si ni ya oogun oloro to gbemi.
Laarin ọjọ kan tawọn oṣiṣẹ NDLEA fi n sọ ọ tọwọ tẹsẹ, o ya idi mejidinlaadọrin oogun oloro heroin ti gbogbo rẹ lapapọ si to iwọn ẹgbẹrin giramu.
Ẹmẹẹta ọtọọtọ ni Abibu fi ya igbe oogun oloro yi laarin ọjọ Kẹrinta oti ikẹẹdogun, oṣu Kẹjọ.
- Kí ló lè mú ìjọba pàṣẹ pé kí wọ́n ka gbogbo ẹranko igbó àti ẹja inú omi?
- Afurasí tó gbé oògùn olóró lọ sílé ìjọsìn ní ọwọ́ NDLEA bá tẹ̀ẹ́ kó tó ké Hallelujah
- Àwọn ajínigbé tú àwọn ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ Bethel mẹ́ẹ̀dọ́gún míràn sílẹ̀
- Ọmọ ọdún márùn-ún tó jẹ́ ògbóntagí èdè Yorùbá, Adigun Olowe jẹ oyè nílùú Eko
- Àwọn jàndùkú afẹ̀mí-ṣòfò ṣekúpa èèyàn 24 ní Kaduna àti Katsina lọ́jọ́ kan ṣoṣo














