Kaduna Kidnap: Àwọn ajínigbé tú àwọn ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ Bethel mẹ́ẹ̀dọ́gun míràn sílẹ̀

Kaduna Kidnap: Àwọn ajínígbé tú àwọn ọmọ akẹkọ̀ọ́ Bethel mẹ́ẹ̀dọ́gun mííràn sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, The Nation

Mẹẹdogun ninu awọn ọmọ ọgọrin to ku ninu awọn ti ajinigbe ji gbe ni ile ẹkọ Baptist Bethel ni ipinlẹ kaduna ti tun gba itusilẹ.

Ni ọjọ karun osu, keje, ọdun 2021 ni awọn ajinigbe wọ ile ẹkọ naa ni agbegbe Damishi ni ijọba ibilẹ Chikun ti wọn si gbe akẹkọọ igba ati mọkanlelogun.

Ní ọjọ karunlelogun ni wọn tu awọn mejidinlọgbọn silẹ lẹyin ti awọn obi san aadọta miliọn Naira.

Lẹyin eyi ni wọn tun ni ki wọn san ọgọrin miliọnu naijra miiran lati tu awọn ọgọrin toku silẹ ni ahamọ wọn.

Iroyin sọ pe wọn tun san owo itusilẹ miiran lati gba awọn mẹẹdogun yi, sugbọn ko si ẹni to le fi idi rẹ mulẹ iye ti wọn tun san.

Àkọlé fídíò, Yoruba Nation: Mo faramọ́ àtúntò 'Restructuring' tí kò lọ́wọ́ ìṣèlú nínú- Oba Ahmed Adeku

Lasiko to n fi idi ọrọ naa mulẹ lowurọ ọjọ Aje alaga ẹgbẹ ọmọ lẹyin kristi (CAN) ẹni ọwọ Joseph Hayab sọ pe mẹẹdogun ni wọn tu silẹ loru Satide.

Àwọn ajínígbé tú àwọn ọmọ akẹkọ̀ọ́ Bethel mẹ́ẹ̀dọ́gun mííràn sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, The Nation