Bethel Baptist kidnap: Àwọn ajínigbé tú 28 nínú akẹ́kọ̀ọ́ 121 Bethel Baptist tí wọ́n jígbé sílẹ̀

Mejidinlọgbọn ninu awọn akẹkọọ mọkanlelọgọfa tawọn ajinigbe gbe lọ lati ile ẹkọ Bethel Baptist loṣu to lọ nipinlẹ Kaduna.
Pẹlu omije loju lawọn obi awọn akẹkọọ naa fi pade ara wọn lẹyin ti wọn ti lo ogunjọ lakata awọn janduku ajinigbe.
Ọkan lara awọn oludasilẹ ile ẹkọ naa, Rev John Joseph Hayab sọ fun BBC pe awọn ajinigbe naa gba lati tu awọn akẹkọọ naa silẹ lẹyin ti wọn jiroro pẹlu obi awọn ọmọ naa.
- Àwọn jàndùkù ajínigbé mú bábá tó gbówó ''ransom'' lọ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jígbé mọ́lẹ̀
- Ẹ̀mí mímọ́ ló ní kí n múra lài wọ bùbá láti ṣe ọjọ́ ìbí mi torí pé ... - Òṣèré Clarion Chukwura
- Sanwo-Olu ṣàlàyé ohun táwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá ń ṣe lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho
- Wo àwọn ẹ̀sùn tí ìjọba Nàìjíríà fi kan Olóyè Sunday Igboho
- Sunday Igboho, ìsáǹsá rẹ̀ kò lé sá mọ́ wa lọ́wọ́, mímú lá mú ọ - DSS fọwọ́ gbáyà
- Isó fààá leè jẹ́ kí ẹ kò Covid-19 níbi tí o ba fún pọ̀! Ẹ fura o!
Amọ ko sọ boya awọn obi awọn akẹkọọ ti wọn jigbe sanwo itusilẹ ki wọn to tu awọn ọmọ naa silẹ.
Ṣugbọn Rev Hayab ni o ṣeeṣe ki awọn obi awọn akẹkọọ ti san owo itusilẹ ki wọn to fi wọn silẹ.
Rev Hayab sọ pe o ti rẹ awọn ọmọ naa nigba tawọn ajinigbe fi wọn silẹ lalẹ ọjọ Abamẹta.

Ni owurọ ọjọ Aiku ni awọn akẹkọọ ọhun lanfaani lati pade awọn obi wọn lẹyin ti wọn ṣe ayẹwo ara fun wọn tan.
Ọjọ karun un oṣu keje ni awọn janduku ajinigbe yabo ile ẹkọ Bethel Baptist nibi ti wọn ti ji awọn akẹkọọ naa gbe lo.
Koda awọn ajinigbe ọhun tun yinbọn pa awọn ẹṣọ eleto abo to n ṣọ ilẹ ẹkọ naa.
Ijọba ipinlẹ Kaduna ko tii sọ ohun kan lori itusilẹ diẹ lara awọn ọmọ ile ẹkọ Bethel Baptist naa.












