Sunday Igboho: Ìdí tí agbẹjọ́rò fi ní ó sàn kí Sunday Igboho kú sí Benin ju kí wọ́n dáa padà sí Nàìjíríà lọ

Oríṣun àwòrán, sunday_igboho1
Amofin Ibrahim Salami to jẹ ajijagbara nilẹ Yoruba, Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ti ṣalaye pe ọna kẹkẹ ni Igboho gba lati Naijiria de orilẹede Benin.
Salami to jẹ Ọjọgbọn ni fasiti kan lorilẹede Benin ni ọna ẹyin ni oun ati iyawo rẹ, Ropo gba de Benin.
Salami sọ pe Igboho ko tapa si ofin kankan ni orilẹede olominira Benin, wọn ko ri iwe igbelu Benin lọwọ rẹ.
- Ìdájọ́ jáde! Ilé ẹjọ́ ti ní kí Sunday Igboho ṣì wà ní àhámọ́ ní Cotonou!
- Sanwo-Olu ṣàlàyé ohun táwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá ń ṣe lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho
- Ó nira fún Sunday Igboho láti jẹun ní àtìmọ́lé ọlọ́pàá torí wọ́n dè é lọ́wọ́- Agbejọ́rò
- Ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ lọ ní ìrọwọ́-rọsẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun- Kọmíṣọ́nnà
- "Ẹ̀yin àgbà amòfin nílẹ̀ Yoruba, ẹ kó lọ sí Cotonou láti gbèjà Sunday Igboho"
- Gbaga ọlọ́pàá ni Igboho ti ń lo òpin ọ̀sẹ̀, ilé ẹjọ́ ilẹ̀ Benin kò jókòó lọ́jọ́ Ẹtì
- Adájọ́ pàṣẹ pé kí DSS kó èèyàn méjìlá tó kó nílé Igboho wá sílé ẹjọ́
- Ẹ̀mí mímọ́ ló ní kí n múra lài wọ bùbá láti ṣe ọjọ́ ìbí mi torí pé ... - Òṣèré Clarion Chukwura
- Kí ló ṣẹlẹ̀ tí Tinubu kò fi kópa nínú ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Eko?
- Isó fààá leè jẹ́ kí ẹ kò Covid-19 níbi tí o ba fún pọ̀! Ẹ fura o!
''Iwe igbelu orilẹede Naijiria ati Germany ni wọn ba lọwọ Igboho.
Nitori ijọba orilẹede Naijiria ni ijọba Benin fi mu Igboho niluu Cotonou.
Ijọba Naijiria ṣalaye sọ fun ijọba Benin pe Igboho ẹsun mẹta ni Igboho ṣẹ.
Àwọn ẹ̀sùn tí ìjọba Nàìjíríà fi kan Olóyè Sunday Igboho tí wọ́n kà jáde ní Cotonou
Akọkọ ni pe o ko ibọn pamọ sile, o si tun n fi n ṣe fayawọ ibọn.
Wọn tun sọ pe Igboho n lo awọn eeyan lati da ilu ru.
Ẹlẹẹketa ni pe Igboho fẹ pin orilẹede Naijiria si meji tabi mẹta.
Ṣugbọn awọn agbẹjọro Igboho sọ fun ile ẹjọ pe ko si otitọ kankan ninu awọn ẹsun ti wọn fi kan an.
Ohun to ṣe pataki fun awa agbofinro Igboho julọ ni pe a ko fẹ ki wọn gbe Igboho pada si Naijiria.
O tẹ wa lọrun ki Igboho ku si orilẹeee Benin ju ki wọn gbe pada lọ si orilẹede Naijiria lọ.
Pẹlu gbogbo ohun ti ajọ DSS ṣe nile rẹ, bii igba pe a gbe ranṣẹ fun iku ni ti wọn fi le gbe pada si Naijiria.
O san ko ko ku si Benin ju ki wọn lọ pa a bi ẹran lọ ni Naijiria.
















