Haunted house sale: Ẹ wo arákúnrín tó ń ta ilé àwọn òkú fún àwọn tó ní ìfẹ́ síi

Àkọlé fídíò, Japan: Ẹ wo arákúnrín tó ń ta ilé àwọn òkú fún àwọn tó ní ìfẹ́ sí

Iṣẹ ti Akira yan laayo ni lati ma a ta awọn ile ti ẹni to ni i ti ku, boya wọn pa abi o pa ara rẹ.

Akira to fẹran iṣẹ to yan laayo naa ni awọn ọdọ ni o ma n ra awọn ileyii lọwọ ohun nitori awọn ko bẹru bi awọn agbaagba.

"Wọn ti pe mi si ile kan ri to jẹ pe iboji mẹẹdogun lo wa nibẹ to si wa lori oke tente".

Amọ o ni bi iye awọn eniyan to wa lorilẹede naa ṣe n lọ ilẹ si ti jẹ ki awọn eniyan ma ni ifẹ si iru awọn ile bẹẹ mọ, amọ oun ti ta iru ile bẹẹ to le ni ẹẹdẹgbẹta fun awọn eniyan.