Bandits killings: Àwọn jàndùkú agbébọn gbẹ̀mí èèyàn 24 ní Kaduna àti Katsina lópin ọ̀sẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn janduku agbebọn afẹmi-ṣofo tun ṣọṣẹ lọjọ Aiku, ọjọ kejilelogun oṣu kẹjọ nipinlẹ Kaduna ati Katsina.
Lọjọ Abamẹta lawọn kọlọnbiti ẹda ọhun kọkọ yabo awujọ Duba ni ijọba ibilẹ Batsari nipinlẹ Katsina nibi ti wọn ti ṣekupa eeyan mejila.
Eeyan mejila mii tun dero ọrun labule Mado, ni ijọba ibilẹ Zangon Kataf nipinlẹ Kaduna lẹyin ti ija bẹ silẹ laarin awọn darandaran atawọn eeyan abule naa to fẹ gbẹsan.
- Àwọn ajínigbé tú àwọn ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ Bethel mẹ́ẹ̀dọ́gún míràn sílẹ̀
- Àjọ SERAP gbé Buhari lọ sílé ẹjọ́ lórí N106bn tí wọ́n ló d'àwátì láwọn ilé iṣẹ́ ìjọba
- Ìdí rèé tí PDP kò ṣe tíì wọlé ìbò gómìnà l'Eko láti 1999 di àkókò yìí- Bode George
- Ẹ dẹ́kun lílo Kurani àti Bibeli nìkan láti fi búra fún àwọn olóṣèlú wa, ẹ jẹ́ ká fí ńkan ìṣẹ̀mbáyé kún un- Oba Ogboni Iwase
- Kí ló lè mú ìjọba pàṣẹ pé kí wọ́n ka gbogbo ẹranko igbó àti ẹja inú omi?
- Ọmọ ọdún márùn-ún tó jẹ́ ògbóntagí èdè Yorùbá, Adigun Olowe jẹ oyè nílùú Eko
Batsari nibi ti wọn ti pa eeyan mejila ni ipinlẹ Katsina jẹ ibode awọn janduku afẹmi-ṣofo ti n ṣọṣẹ lẹkun iwọ oorun ariwa Naijiria.
Awujọ Batsari tun pa aala pẹlu igbo Rugu to wa lara ijọba ibilẹ mẹwaa tawọn janduku yii maa n ṣe ikọlu si.
Alukoro ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kaduna, Isa Gambo fidi rẹ mulẹ pe awọn janduku agbebọn to le lọdunrun yabo ijọba ibilẹ Zangon Kataf pẹlu oriṣiiriṣii ibọn ati ohun ija oloro ni bii ago mẹsan ku iṣẹju mẹẹdogun lalẹ ọjọ Abamẹta.
Gambo ṣalaye pe awọn janduku ọhun da ibọn dolẹ kete ti wọn de abule Duba, lẹyin naa ni wọn bẹrẹ si ni jale ninu awọn ṣọọbu, ti wọn si tun ji awọn ẹran ọsin eeyan ilu naa.
Alukoro ile iṣẹ ọlọpaa ni eeyan mẹfa lo farapa yatọ si eeyan mejila to gbẹmi mi nibi iṣẹlẹ ọhun.
O fidi rẹ mulẹ pe awọn ọmogun atawọn ọlọpaa ṣi n tẹsiwaju lori ati le awọn janduku ọhun kuro ni Kaduna.
Gambo ni awọn eeyan mẹfa to ṣeeṣe nibi iṣẹlẹ ọhun ti n gba itọju nile iwosan.















