Yahaya Bello vs Tinubu: Joe Igbokwe ní ọmọdé kò lè ṣèjọba Nàìjíríà, Tinubu ló ní ìrírí jùlọ

Tinubu and Yahaya Bello

Oríṣun àwòrán, others

Alukoro ẹgbẹ osẹlu APC nipinlẹ Eko tẹlẹ, Joe Igbokwe naa ti fesi si ọrọ ti gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello to sọ pe ki Bola Tinubu fawọn ọmọde ninu ẹgbẹ laaye lati dupo aarẹ lọdun 2023.

Igbokwe sọ fun BBC Yoruba pe Ọlọrun nikan lo le ni ki Tinubu maa jẹ aarẹ Naijiria lọdun 2023.

Igbokwe to jẹ ọkan lara awọn oludamọran si Gomina Babajide Sanwo-Olu ṣalaye pe ayafi ti Tinubu fun ra rẹ ba yi ọkan rẹ pada wi pe oun ko dije mọ nikan loku.

''Iriri ṣagba ọgbọn, ati pe ẹru ajanaku lọrọ orilẹede Naijiria, kii ṣe ẹru ọmọde.

Joe Igbokwe ni: Orilẹede Naijiria tobi ju ohun ti ọmọde le ṣe adari rẹ lọ nitori ita to ba tọ si imu ni a maa fi n re imu.

Ko si ẹni tun ti ni iriri ti Tinubu ni lagbo oṣelu ni Naijiria.

Bello kan n sọ ọrọ tiẹ ni nitori ara rẹ, ṣugbọn Aṣiwaju ti rin jina lori irinajo rẹ lati jẹ aarẹ Naijiria.

Àkọlé fídíò, Babatunde Gbadamosi: Mo ta gbogbo dúkìá mi lásìkò kan kí ń tó padà di eèyàn lónìí

O yẹ ki Naijiria tilẹ sanwo fun Tinubu ni lati wa jẹ aarẹ orilẹede yii.

Nitori ohun ti Tinubu yoo ṣe to ba di aarẹ Naijiria pọju.

Anfani nla lo maa jẹ ki fawọn eeyan Naijiria ti Tinubu ba le jẹ aarẹ orilẹede Naijiria,'' Igbokwe lo sọ bẹẹ.

Ọmọwe Abdul-Azeez Olajide Adediran ati Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Facebook/Jandor

Tinubu lẹ́tọ̀ọ́ láti dupò ààrẹ lẹ́gbẹ́ APC gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọdé náà ti lẹ́tọ̀ọ́ - Jandor

Jandor ní àti ọmọdé àti àgbà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti díje fún ipò ààrẹ lọ́dún 2023

Eekan ẹgbẹ oṣelu APC to tun ṣagbatẹru ipolongo Lagos4Lagos ṣaaju ibo gomina ipinlẹ Eko ọdun 2023, Ọmọwe Abdul-Azeez Olajide Adediran.

Oun ni ọpọ mọ si Jandor ti fesi si ọrọ ti gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello sọ pe ki Aṣiwaju fawọn ọmọlẹyin lanfani lati dupo aarẹ lọdun 2023.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Ọmọwe Adediran ni ko si ẹni ti ko lẹtọọ lati dupo aarẹ lọdun 2023, ki ba ṣe ọmọde tabi agba.

Àkọlé fídíò, Badagry: Ojú ọ̀nà àrèmabọ̀ fáwọn ẹrú tó ń lọ sókè òkun

Jandor sọ pe ko si ọrọ ninu ohun ti gomina Bello sọ nitori pe iwe ofin orilẹede Naijiria fun gbogbo eeyan lanfani lati dije fun ipo aarẹ to ba wu wọn.

Jandor yii lo ti n polongo pe Eko fun Eko lo maa bade ninu ibo gomina ipinlẹ naa lọdun 2023.

Jandor ni o da oun loju pe oun ni oun maa jẹ gomina ipinlẹ Eko lasiko idibo to n bọ.

Àkọlé fídíò, Yoruba Nation: Mo faramọ́ àtúntò 'Restructuring' tí kò lọ́wọ́ ìṣèlú nínú- Oba Ahmed Adeku

Tinubu, fi ipò Ààrẹ sílẹ̀ fún àwa ọmọ rẹ kí o lè lọ sinmi- Yahaya Bello

Gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello ti sọrọ lori idi ti eekan ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu ko ṣe gbọgọ gbe apoti ibo Aarẹ lọdun 2023.

Bello sọ pe o ti di dandan ki awọn aṣaaju ẹgbẹ APC ṣatilẹyin fun ọdọ to ba nifẹ lati gbe apoti idibo Aarẹ, ati pe adehun to wa laarin Tinubu ati Aarẹ Buhari ko lẹsẹ nilẹ.

Bo tilẹ jẹ pe Tinubu ko ti sọ ni gbangba pe oun fẹ dije du ipo Aarẹ, ṣugbọn patako ajuwe ipolongo rẹ ti wa kaakiri laarin ilu, paapaa nipinlẹ Eko.

Bello sọ fun awọn akọroyin pe oun bọwọ fun Tinubu gẹgẹ bii agba ọjẹ ninu oṣelu, amọ asiko ti to fun lati lọ sinmi.

Bello ni "Tinubu jẹ ọkan gboogi lara awọn aṣaaju wa, mo si gboriyin fun fún awọn iṣẹ to ti ṣe sẹyin ati akitiyan rẹ lati gbe ẹgbẹ wa de oke agba."

"Ṣugbọn tọwọ-tọwọ ni mo fi n sọ fun Tinubu gẹgẹ bii ọmọ pe ko lọ sinmi, ko fi ipo aṣaaju silẹ fun awọn ọmọ rẹ."

"Niṣe lo yẹ ki Tinubu kọ awọn ọmọ to wa lẹyin rẹ bi wọn ṣe n ṣe eto ilu, ko si maa woye bi a o ṣe tun ilu ṣe loju aye rẹ."

Àkọlé fídíò, Wikipedia: Ẹ̀nìkan sọ fún mi pé iṣẹ́ ìdọ̀tí ni màá ṣe ni mo ṣe ń ta ìwé

Bello ni Tinubu lẹtọ labẹ ofin lati dije du ipo Aarẹ, oun si rọ awọn araalu lati fun ni ọwọ to tọ si.

Nigba to n fesi si ibeere pe boya o ṣeeṣe ki Tinubu fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ ti ẹgbẹ naa ba kọ lati fun ni anfani lati dije, Bello ni o ṣoro ki eeyan kọ ile, ko tun fi ọwọ ara rẹ wo ile naa.

O ni "Mi o lero pe Tinubu le ṣe bẹẹ, ko ṣeeṣe ki eeyan kọ ile ko tun fi ọwọ ara rẹ wo ile ọhun, Tinubu ti kọja irufẹ iwa bẹẹ."

Ni ti erongba rẹ lati du ipo Aarẹ, gomina ipinlkẹ Kogi naa sọ pe oun yoo fun gbogbo awọn to n fẹ ki oun du ipo Aarẹ ni esi ti akoko ba to.

Àkọlé fídíò, Yoruba Nation: Ààrẹ ẹgbẹ VOR sọ pé kí ọmọ Yorùbá di ààrẹ Naijiria kọ́ ni ọ̀nà àbáyọ

Ẹwẹ, ẹgbẹ awọn ọmọ Yoruba kan, Yoruba Welfare Group, YWG, ni Tinubu ni awọn n fẹ ko di Aarẹ Naijiria lẹyin Mohammadu Buhari.

Aarẹ ẹgbẹ naa, Abdulhakeem Alawuje sọ fun awọn akọroyin pe aṣiwaju ni Tinubu, o si ti ni iriri yẹ lati tukọ Naijiria, nitori naa Bola Tinubu ipo Aarẹ kan.

Àkọlé fídíò, Oba Ogboni Abalaye n fẹ́ kí wọ́n o má a fi ẹ̀sìn àbáláyé búra fún àwọn olóṣèlé Naijiria