Shuwa Arab Edo: Àrífin ni ìfinijoyè Sultan of Shuwa Arab sí àṣà àti àwọn èèyàn Edo

Gomina Godwin Obaseki ati Sultan Shuwa

Oríṣun àwòrán, Punch/godwin obaseki/facebook

Ijọba ipinlẹ Edo ti sọ pe ayẹyẹ ifinijoye bi ti Sultan of Shuwa Arab, jẹ iwa afojudi si aṣa ati ìṣe awọn eniyan ẹya Edo.

Ati pe awọn to ṣagbatẹru ifinijoye naa fẹ ẹ fi iwa ikonimọra awọn ẹya Edo wọlẹ.

Akọwe ijọba ipinlẹ Edo, Osarodion Ogie lo sọ eyi ninu atẹjade to fi sita nitori awuyewuye to waye lori ayẹyẹ ifinijoye naa.

Àkọlé fídíò, Oba Ogboni Abalaye n fẹ́ kí wọ́n o má a fi ẹ̀sìn àbáláyé búra fún àwọn olóṣèlé Naijiria

Iroyin jade pe awọn eeyan ẹya Shua lati Ariwa Naijiria fẹ ẹ fi Sultan jẹ ni Benin.

Ọgbẹni Ogie sọ pe iru iwa bẹẹ le fa rogbodiyan ni ipinlẹ na. O ni ẹṣẹ ni fun ẹnikẹni lati pe ara rẹ ni oloye tabi ọba ti ofin ifinijoye ipinlẹ naa ko da mọ tabi fọwọ si.

Eyi waye nitori bi awọn ọdọ kan nilu Benin ṣe bẹrẹ awuyewuye lori bi ẹgbẹ kan lati ipinlẹ Borno ṣe n gbeero lati fi Sultan of Shuwa Arab jẹ nilu Benin.

Ẹni to jẹ Aarẹ ẹgbẹ ọmọ bibi ilu Benin kaakiri agbaye, Curtis Eghosa Ugbo, sọ fun BBC Pidgin pe awọn ko le faaye gba iru ifinijoye bẹẹ, nitori pe ko ṣe e ṣe ki wọn o ni ọba meji nilu Benin

Ọgbẹni Ugbo sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ Shuwa arab ti kọkọ kọ lẹta si Aafin Ọba pe awọn fẹẹ wa ki, o ni ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ nigba ti awọn ri ti iwe ipe si ayẹyẹ ifinijoye Sultan n lọ kiri igboro.

Iwe ipe si ibi ayẹyẹ ifinijoye to da wahala silẹ re e

Oríṣun àwòrán, oda

Àkọlé àwòrán, Iwe ipe si ibi ayẹyẹ ifinijoye to da wahala silẹ re e

O ni eyi yatọ si nkan ti wọn kọ sinu lẹta ti wọn kọ.

"Ṣe o ṣe e ṣe ki n lọ si Ariwa Naijiria, ki n sọ pe mo fẹ ẹ jẹ Enogie ilu wọn? Koda, ko ṣe e ṣe ni ipinlẹ Delta to sun mọ Edo. Arifin lo jẹ fun ilu naa."

Bakan naa ni Aafin Ọba ilu Benin sọ pe inu awọn dun si bi ijọba ipinlẹ Edo ṣe koro oju si iwa afojudi ti awọn eeyan hu nipa gbigbeero lati fi Sultan jẹ ni Edo.

Ninu ikede ti wọn fi sita lori Facebook wọn, wọn ni awọn fi ara mọ igbesẹ ijọba lori ọrọ naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa paapaa sọ pe awọn n wo ibi ti ọrọ naa yoo ja si, nitori pe awọn ko ti i ri aṣẹ gba lọwọlọwọ ẹnikẹni lati da si ọrọ naa.

Àkọlé fídíò, Oba Gbolahan Timson shomolu: Obasanjo ti jẹ́wọ́ pé 'Mistake' ni Buhari ṣùgbọ́n...