EFCC ṣàlàyé lórí ohun tí wọ́n wá lọ sí ilé Dorothy

EFCC ṣàlàyé ṣé lórí òhun tí wọn wà lọ sí ilé Dorothy-ẹ gbọ́ n tí wọn sọ

Oríṣun àwòrán, The ddorathybachor/instagram

Ajọ to n gbogun ti iwa jegudujera lorileede Naijiria EFCC ti sọ pe lootọ l'awọn lọ si ile gbajumọ ori ayelujara Dorothy Bachor.

Dorothy Bachor jẹ gbajumọ ori ayelujara ti o fi gba kan kopa ninu idije ile ẹlẹgbọn Big Brother Naija.

Wọn fidi ọrọ yi mulẹ loju opo Facebook wọn ni idahun si iroyin to gbode pe wọn ja wọ inu ile rẹ lowurọ kutu ọjọ Kẹtalelogun oṣu yi.

EFCC ṣàlàyé ṣé lórí òhun tí wọn wà lọ sí ilé Dorothy-ẹ gbọ́ n tí wọn sọ

Oríṣun àwòrán, Thedorothybachor

Wọn fidi ọrọ yi mulẹ loju opo Facebook wọn ni idahun si iroyin to gbode pe wọn ja wọ inu ile rẹ lowurọ kutu ọjọ Kẹtalelogun oṣu yi.

Atẹjade ti ajọ naa fi sita sọ pe iwadii awọn fi han pe awọn ọmọ yahoo yahoo lo wa nibi ile alakọpọ ti Dorothy n gbe ladugbo Lekki ati pe awọn ri mẹsan mu ninu wọn lasiko tawọn lọ sibẹ.

''Ile igbe arabinrin Bachor wa lara awọn ile ti a lọ.A kan ilẹkun nibẹ ti a si ṣalaye pe lati EFCC la ti wa.

Lẹyin ti aburo rẹ obinrin ko jẹ ka wọle la ba fipa ja lẹkun ki wọn ma ba ko ẹri pamọ''EFCC ṣalaye pe bi eeyan ko ba jẹ fufu ara ko ni fu nitori naa ko yẹ ki ẹnikẹni di awọn agbofinro lọwọ lati se iṣẹ wọn.

EFCC ṣàlàyé ṣé lórí òhun tí wọn wà lọ sí ilé Dorothy-ẹ gbọ́ n tí wọn sọ

Oríṣun àwòrán, Thedorothybachor

Ninu alaye ajọ naa, wọn ni ko si ootọ kankan ninu iroyin to gba igboro pe arabinrin Bachor jade ni ihoho sawọn.

Ajọ naa ni lasiko tawọn lọ, arabinrin Dorothy ko si ninu ile naa ati pe iroyin ẹlẹjẹ wọn yi lawọn gbajumọ ori ayeluja bi tiẹ maa n gbe kaakiri nipa awọn.

EFCC wa tẹnumọ pe eeyan mẹsan lawọn mu ni ile Dorothy tawọn fura si pe wọn ṣiṣẹ yahoo yahoo nibi ile alakọpọ ti Dorothy n gbe.

Saaju ni Dorothy fun ara rẹ ti bọ soju opo INSTAGRAM rẹ to si ni awọn oṣiṣẹ EFFC le eeyan kan wọ ile igbe ti oun wa ni nkan bi ago mẹrin owurọ kutu.

Ninu ọrọ rẹ, o ni iṣẹlẹ yi ko iporuru ọkan ba ohun ati mama oun debi pe aya awọn bẹrẹ si ni ja.