Apostle Suleiman vs Chioma: Apostle Suleiman ti sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀sùn ti Chioma fi kan

Olùdásílẹ̀ Omega Fire Ministry (OFM) Apostle Johnson Suleman ti fèsì sí ẹ̀sun ti oṣèré Nollywood Chioma Ifemeludike fi kan pe àwọn jọ ni ìbálòpọ̀ lásìkò kan sẹ́yìn.
Ó sọ pé inú kò bi òun rárá lórí ọ̀rọ̀ náà pàápàá jùlọ àwọn tó n bẹnuj àtẹ́ lu òun lórí ayélujára nítori ẹ̀sùn náà.
Sááju nínú fọ́ran kan tó é ni iṣẹ́jú méjìlá ni Chioma ṣàlàyé ìbáṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Apostle Suleman tí ó sì gfún òun ni owó tabua lásìkò tó n múrà láti lọ sìrú ilẹ̀ baba.
Chioma ni ìdí tí òun fi jáde wá láti jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ òun ni pé, òun ti gba jésù ni olúwa àti olùgbàlà òun nítorí náà ó pọndadan láti jẹ́wọ́ gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí òun ti ṣẹ sẹ́yìn.
Nínú fọ́ràn kan ni Apostle Suleman ti ṣàlàyé fún àwọn ọmọlẹ́yin rẹ̀ nínú ijọ pe gbogbo àwọn ẹ̀sùn ti Chioma fi kan kò tu irun kankan lára òun.
" Kíni ìdí tí ẹ̀ ó fi máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún ẹni ti kò ni ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn nígbà kank?
Inú bími gan ni ni àná, Mo rí àwọn àtẹẹ̀jíṣẹ́ tí wọ́n ni sọ fún mi pé kí ń ma bìkítà.
" Wo ojú mi, tí o bá rí mi ti mo ba ọkàn jẹ́, o lè bá mi sọ̀rọ̀ ìtùnú fún mi. Se mo jọ ẹni to nílò ọ̀rs ìtùnú ni?
Kò sí ìrẹ̀wẹ̀sì fún mi, bákan náà ni inú kò bími sí àwọn tó ń bẹnu àtẹ́ lù mí lórí ayélujára."
Suleman ní iṣẹ́ tí ọ̀rún gbé lé òun lọ́wọ́ ni òun kóju mọ́, sùgbọ́n àwọn tó n sọ̀rọ̀ lójú ọpọ́ ìkànsíraẹni gbogbo kan ń sọ̀rọ̀ nítorí nǹkan ti wọn ri ká lórí ayélujara ni.
Ẹkò le ms mí bi mo ṣe mọ ara mi, ko ṣeéṣe.
Ẹ tẹ̀síwájú láti máa ṣe nǹkan ti ẹ n ṣe, èmì náà yóò máa tẹ̀sí'wa'jú láti máa ṣe nǹkan ti mò n ṣe.
" Mo gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ ẹni tó rán mi"
Ọ ní òun ti fi ojú fo gbogbo àwọn fọ́rán ti wọ́n ṣe ni ìlòdì sí òun.
Ìyàwó mi ló lé ṣe ẹlẹ́rìí mi, gbogbo àwọn fọ́rán ti àwọn ènìyàn ṣe lòdì sí mi, kò sí ẹyọkan báyìí tí mo tii wò.
Gbogbo yín ni ẹ ti wòó afi èmi nìkan ni mi kò tíì wòó.
"Nǹkan ti ènìyàn kò bá rí , kò le ṣe nǹkankan fun ènìyàn.
Ẹnìkan fi fọ́nrán náà ṣọwọ́ sí mi lánàá, àsìkò yẹn gan ni mo fi ọwọ́ kan fóònù mi kẹ́yìn.
Mo sábò lórí ọkàn kí ń le maa ni àjọṣepọ̀ tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run.
Ẹ sinmi ọ̀rọ̀ ẹ̀yin ṣíṣọ. Gbogbo nǹkan ti ko bá ni ru ọkàn mi sókè, èmi kìífi aaye gbá. Apostle Suleiman lo sọ bẹ́ẹ̀.

















