Omoyele Sowore ní Apostle Suleiman o le gba onidúro òun

Olùdásílẹ̀ ilé iṣẹ́ Sahara, Omoyele Sowore tí kọ àǹfàní tí ààrẹ ilé ijọsin Omega Fire Ministries Worldwide Àpóstélì Johnson Suleiman fún un láti gba oníduró rẹ̀.
Suleiman ti sọ ṣááju lórí àtẹjísẹ́ twitter rẹ̀ pé òun gba a lérò láti gba onídúro Soworẹ bótilẹ jẹ́ pé o ti tẹ asọ àgbà ọ̀pọ̀ ènìyàn mọ́lẹ̀ sẹ́yìn pàápàá jùlọ òun, síbẹ̀ òun ni ìgbàgbọ́ pé kò tọ́ kí àwọn máa wò ó níran láti rà s'ẹ́wọ̀n.
Ẹ̀wẹ̀, ọkan nínú àwọn agbẹ́jọrò Sowore Inibehe Effiong wá sàlàyé pé Suleiman o sí ni ipò láti gba oníduro Sowore tó jẹ́ ajìjàgbara.
Effiong ní ilé ẹjọ́ sàlàyé dáradára pé ẹni ti yóò gba oníduro Sowore gbọ́dọ jẹ́ olùgbé ìlú Abuja, àti pé ẹni ti yóò dásọ fun ni tọrun rẹ̀ ni à ń kọ́kọ́ wò, àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ̀ pọ̀ lọ́run rẹ̀ pẹ̀lú, nítori náà oun àti Soworẹ o lé jọ tò pọ̀ si ìhà kan náà.
Bakan náà lo fi kún un pé, ìjọba apapọ ti sọ ọ̀rọ̀ Sowore di tí òṣèlú, àwọn ǹkan ti wọ́n si gbé silẹ̀ láti gba oníduro Sowore kò si ẹni to le sán.
Àpọsítélì Suleiman ló ṣeéṣe kí òun sàn owó onídùúró Sowore

Oríṣun àwòrán, Google
Ko le buru buru ki o ma ku ẹnikan mọ eeyan lọrọ bi Aposteli Suleiman ṣe ni oun n gbero lati san owo oniduro Omoyele Sowore to wa ni ahamọ.
Ọgọrun miliọnu ni ile ẹjọ la kalẹ ni owo oniduro fun oloṣelu naa ṣugbọn titi di bi a ṣe n sọrọ yi,ko ti si ni to ṣetan lati san owo naa.
Loju opo Twitter rẹ ni Apọsteli Suleiman ti fi ọrọ yi sita.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ninu alaye to ṣe o ni lootọ ni pe Sowore ṣe ohun to dun awọn eeyan,ṣugbọn ọmọ ẹni ko ni buru buru ka wa le fẹkun pa jẹ.
O fi ibeere sita pe ''Njẹ o wa yẹ ki a tori eleyi ko wa ku si ẹwọn?''
Oṣu Kẹjọ ọdun 2019 ni awọn ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ Naijiria mu Soworẹ ki wọn to gbe lọ si ile ẹjọ.
Ẹsun iditẹgbajọba ni wọn fi kan ṣugbọn lẹyin atotonu agbẹjọro rẹ,ile ẹjọ ni ki wọn tu silẹ lẹyin to ba san owo beeli ẹgbẹrun lọna miliọnu Naira.














