Smart-Cole: Ayàwòrán tó ń ya àwòrán àwọn alágbára ayé tóò mọ̀

Sunmi Smart-Cole ẹni ọdun mejidinlọgọrin taju kan wẹhin wo, o ranti igba to ṣi jẹ ọdọ langba ṣugbọn to pa iṣoro ati idamu idile rẹ ti to si lọ n gbe pẹlu ọrẹ rẹ kan ni PortHarcourt.
O ti pari ileewe alakọbẹrẹ ṣugbọn ko rọna ati tẹsiwaju. Pẹlu gbogbo owo to pa latara iṣẹ olukọni to n ṣe nileewe igberiko, lo fi ra ẹrọ rẹdio asọrọmagbesi nigba naa.
Lo ba bẹrẹ si ni fẹran lati maa gbọ iroyin BBC. Ko pẹ ko jina lẹyin eyi ti ẹrọ rẹdio naa di olukọni fun un tawọn atọkun eto ati akọroyin si di olukọ rẹ.

Eyi jẹ ko le gbaradi fun itẹsiwaju ẹkọ rẹ eyi to ti lero ṣugbọn ti ko sagbara fun un.
"Araarọ, mo ma tete ji dide lati gbọ iroyin igba de igba lori rẹdio". O ni "mo maa n nifẹ si iṣọwọ sọ oyinbo wọn lọna ti ilẹ Britain".
Ko to di pe o n ṣe eleyii, o ma n ra awọn iwe iroyin igba de igba, ti awọn ọrọ tuntun to ma n kọ ninu wọn si ma n da a lọrun.

"Iṣoro to kan wa nibẹ ni pe "boo mọ gbogbo ọrọ naa, bawo lo ṣe fẹ pe e jade lẹnu?. O ni ilu PortHarcourt t'oun wa pẹlu ayida ede Gẹẹsi ti wọn ma n sọ tun n da kun iṣoro ni.
"Ọpọ ni eebo ẹnu wọn ko dara to, mi o si fẹ dara pọ mọ wọn".
Ori eto rẹdio BBC ni Smart - Cole ti ma n kọ bi wọn ṣe n pe ọrọ daadaa, to si tun n kọ sinsin ohun bi ti awọn akaroyin wọn.

Nigba to de Eko to dara pọ mọ awọn akẹkọọ ile iwe giga, ọpọ ni ko tilẹ mọ pe ẹkọ rẹ kò tíì kọja ileewe alakọbẹrẹ, ṣugbọn ṣe ni o n jẹ iwuri fun gbogbo awọn to ni gbolohun pẹlu rẹ.
"Mo ni ọrẹbinrin kan to lọ kawe Cambridge nilu Oyinbo. Ọjọgbọn ni baba ati iya rẹ.. O ni itan mi ya oun lẹnu gan to ṣe pe ko ba ma gbagbọ bi mi o ba sọ fun un".
Smart-Cole riṣẹ gẹgẹ bi ọmọ ẹkọṣẹ ayaworan, ṣugbọn wọn da a duro lẹyin oṣu diẹ nigba ti wọn wo akọsilẹ iwe rẹ ti wọn ri i pe ko ni sabuke ileewe alakọbẹrẹ.
Bẹẹ naa lawọn ileeṣẹ kan kọ lati gba a siṣẹ fun idi kan naa.
Ọpọ igba lo ṣiṣẹ lẹyin olorin nni Fela Anikulapo gẹgẹ bii onilu atawọn ẹgbẹ olorin mii.

Nigba to ya, Smart-Cole pinnu lati ṣi ileeṣẹ irun gigẹ, to si tọ baba ọrẹ rẹ lọ fun iranwọ owo lati bẹrẹ. Ibinu ni baba naa fa yọ o!
"O ni oun ti ma n fi mi ṣe apẹrẹ fun awọn ọmọ rẹ ọkunrin, pe mo ma n fọ oyinbo daadaa pe ki wọn fi mi ṣe awokọṣe, lemi wa fẹ lọ ṣe iṣẹ ti ko ja mọ nkankan".
Ṣugbọn lẹyin ti Smart-Cole kọrọ 'lẹ, to ṣe alaye pe oun ko diidi lọ si ileewe kan saan, o ba arakunrin naa lojiji o si tun jẹ idunu fun un.
Lo ba ko owo fun un - £20 ni ile bábà Sunmi ba di aayo gbogbogbo fawọn ọtọkulu ilu ni ipinlẹ Eko. Ṣe lo maa n rọra fi orin Jazz da awọn onibara rẹ lara ya atawọn iwe iroyin igba de igba ti ilẹ okere.

Ọkan lara awọn onibara rẹ pe e si ayẹyẹ kan ni Eko nibi to ti pade ajafẹtọ ọmọniyan ilẹ Amẹrika kan, Jesse Jackson, to pada ni ko wa si ilẹ United States fun ayẹ orin kan lọdun 1971.
Anfani yii mu Smart-Cole lọ forukọ silẹ to si kọṣẹ nipa aworan yiya nileewe kan l'Amẹrika lọdun 1976..
Ọpọlọpọ iṣẹ rẹ lo ri anfani lati ṣafihan rẹ lati ọdun 1978 lati igba naa lo si ti n ṣe afihan kaakiri agbaye.
Lọdun 1983 ti ijọba ologun gbajọba lọwọ alagbada, Smart -Cole gba ipe lati wa jẹ ayaworan akọkọ fun oludari iwe iroyin Guardian ti aworan rẹ si bẹrẹ si ni fara han loju ewe waju iwe iroyin yii ni gbogbo ọjọ Aiku.

Aworan Ibrahim Babangida ninu eyi to fẹyin kẹẹ eyi to ti tan ka gbogbo agbaye bayii ti wọn fi mọ olori orilẹede Naijiria akọkọ, Smart-Cole lo ya a.
O pada goke agba to di oludari agba iwe iroyin Guardian titi di ọdun 1989 to fiṣẹ silẹ di ayaworan aladani.
Lara awọn aworan rẹ to lami laaka lawọn to ya loju popo tabi ninu iloro. Ọjọgbọn kan kọ ọ sinu iwe rẹ pe, kii ba Smart-Cole lojiji pẹlu ẹrọ ayaworan rẹ lati ka ohunkohun to ba bẹ silẹ.

Ọsan ọjọ kan lọdun 1989, ọkọ ologun kan duro niwaju ile Smart-Cole nilu Eko. Awọn aladugbo rẹ si ri i ti wọn n dede gbe e lọ.
Eyi da idamu si wọn lọkan tori wọn ko tilẹ mọ idi ẹsun kankan ti wọn wa gbe e fun.
Amọ ṣa, ṣe ni wọn ri i pe fun rere ni - iyawo olori orilẹede naa lọhun, Maryam Babangida lo fẹ ko wa ya fọto ọmọ rẹ to pe ọdun kan.

Ni Smart-Cole ba di ayaworan ti wọn fun niṣẹ lati maa ya olori orilede nigba naa atawọn idile ilumọọka ni Naijiria, eyi to wa fun ni iyì ati ẹ̀yẹ gẹgẹ bii ayaworan ọmọ Naijiria akọkọ to gbayi lagbaye.
Ko si ayẹyẹ nla kan to tii pe bi ko ba si Smart-Cole nibẹ lati yaworan ti yoo si gbe wọn jade ninu iwe iroyin "This Day" nibi to ti jẹ oludari aworan iroyin.

Nibi to ya aworan de, Smart-Cole fi awọn iṣẹ kan silẹ lati ṣe tawọn eeyan jankan jankan lorilẹede Naijiria bẹẹ si ni ibaṣepọ rẹ pẹlu awọn alagbara fun ni anfani ati kan awọn alagbara agbaye mii naa lanfani.
Fun gbogbo ọdun yii ti Smart-Cole fi fẹran lati maa gbọ BBC, ifẹ rẹ ko dinku bo tilẹ jẹ pe o ti wa n wo ẹrọ amohunmaworan ju rẹdio lọ bayii.
Lonii, Smart-Cole ṣi n yaworan ṣugbọn kii ṣe lati pa owo. O ṣi fẹran ẹrọ ayaworan rẹ to fi n ṣiṣẹ o si gba pe iyatọ gbaa wa laarin eyi to fi ẹrọ ayaworan ya ati eyi to fi foonu ya bi wọn ṣe n ṣe oriṣiriṣi rẹ lode oni.
"O dara fun oni ṣugbọn kii ṣe oun to lee pẹ lailai".













