COZA: Mí o ba ijọ náà ṣe ìpolongo ètò wọ́n-Davido

Oríṣun àwòrán, @davido Instgram
- Author, Yemisi Oyedepo
- Role, Broadcast Journalist
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2
Gbajúgbaja olórin tàkasúfèé David Adeleke ti gbogbo ènìyàn mọ si Davido ti gbarata lóri fọ́nran kan tó n tàn ka lori ayelujara lori oun ati COZA.
Ori atẹjiṣẹ́ twitter rẹ lo ti yari lowurọ̀ oní (Ọjọbọ) pe irọ ni pe oun n polowo eto tuntun ti ijọ Commonwealth of Zion Assembly fẹ ṣe nibẹrẹ ọdun to n bọ.
Fidio naa ṣafihan íbi ti Davido àti ọmọde kan ati obinrin kan ti jọ ń kéde èto ìsìn ọlọjọ mejila kan ti ijọ Common Wealth of Zion Assembly (COZA) fẹ́ ṣe loṣu to m bọ.
Ọ̀pọ̀ ọmọ Naijiria jí lówurọ̀ òní ni wọn ba bẹ̀nu ẹ̀tẹ́ lú ìgbésẹ̀ Davido gẹ́gẹ́ bi wọ́n ṣe ri i nínú fọ́nran náà.
Ṣugbọ́n bí Davido ṣe rii náà ni Davido ti kọ atẹjade kan lati tako fọ́nran náà pé òun kò ní ǹkankan ṣe pẹ̀lú ìpolongo náà.
O ni pé ọmọdebinrin to han nínú fọ́nran náà ni oun ṣe fidio náà fun nitori pe olólùfẹ́ òun ni kii ṣe ijọ COZA rara.

Oríṣun àwòrán, @Davido
Sùgbọ́n, kàkà ki ewé agbọ́n dẹ̀, o dàbi pé àtẹjade naa tún bẹ̀rẹ̀ si ni ru ọ̀rọ̀ míràn síta ni, ọ̀pọ̀ ni ojú kòró ni fọ́nran náà ati pe Davido kò sile so pe òun kò mọ ǹkan ti wọ́n fẹ́ fi ṣe.

Oríṣun àwòrán, Twitter
Nigba ti awọn miran kilọ iṣọra fawọn ijọ iwoyi pe ẹkọ gbigbona n fẹ suuru.

Oríṣun àwòrán, @davido

Oríṣun àwòrán, @davido
Lẹ́yìn gbogbo ọhu-ọhu yìí ni obinrin tó farahàn nínú fọ́nran náà pada wá tọrọ aforijin lọ́wọ́ Davido ninu atẹjade to fi sita pe:

Oríṣun àwòrán, @omalizz
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Omalizz ni ni òun fẹ́ sàlàye ǹkan to ta kókó nínú fọ́nran náà.
O ni òun ya fọ́nran ọhun pẹ̀lú Davido àti ọmọ òun fún ijọ oun tii ṣe COZA, o ní kìí ṣe ijọ lo ni fọ́nran náà wọ́n o si san owo fun Davido láti ṣe e sugbọ́n ona láti pe àkiyesi àwọn eniyan ni oun fi ṣe.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post














