Aarẹ Pakistan: Idájọ ikú ni wọ́n fun Musharraf nitorí ẹ̀sùn Iditẹ̀ gbà ìjọba

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ilé ẹjọ́ kan lorilẹ̀-èdè Pakistan ti dájọ ikú fún adari ológun tẹ́lẹ̀ri Pervez Musharaff nitori ẹ̀sùn idìtẹ̀ gbà ijọba to ṣe lọ́dun 2017 bo tilẹ jẹ́ pé kò si nibẹ̀.
Èyí ni ìgbà àkọkọ ti irú idájọ yìí yóò wáyi láti igba ti ijọba ọlógun ti wà lórilẹ̀-èdè náà. Ibínú ni àwọn ọmọogun fi gba ìdájọ náà "o dàbi ẹni pé àwọn pé àwọn o kọbiara si ètò ìdájọ."
Ọgágun náà ditẹ̀ gbàjọba lọ́dun 1999 ti o si di ààrẹ láti ọdun 2001 sí 2008
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò dáju boya irú idájọ bẹ́ẹ̀ yóò fẹ́sẹ̀ múlọ. Wọn gba ọgágun Musharraf láàye lati kuro ni Pakistan ní ọdun 2016, o si wà ni Dubai.
Idajọ yìí ti wà niwáju ilé ejọ lati ọdun 2013, eyi ni i ṣe pẹ̀lú bi ọgágun Musharaff ṣe fagile lílo iwé ofin nígba to kéde pé oun yóò sàfikun ijọba rẹ̀.

Oríṣun àwòrán, Handout via Getty
Ẹni ọdún mẹ́rindinlọ́gọ́rin ọhún ni òun ń gba ìtọjú ni Dubai ni ti o si fi fọ́nran ilé iwosan náà sinú àtẹjáde tó fi síta sáàju nínú oṣù yìí, o sàpèjúwé ẹjọ ti wọn pé si gẹ́gẹ bi èyi ti kò fidi múlẹ̀.
- Kà nípa ìròyìn mánigbàgbé tí BBC News Yorùbá ṣe láàárín ọdún kan
- Hubert Ogunde rèé, baba àwọn òsèré tíátà
- Bí èèyàn méjì tí ṣé kù nígbà tàwọn jàǹdùkú wọ̀yá ìjà ní ìlú Èkó-Ọlọ́pàá
- Ilé aṣòfin àgbà Nàìjíríà láwọn ṣetán láti buwọ́lù owóyàá $29.96bn
- Ẹ̀wọ̀n tí mo lọ ni ẹ̀san ìwà tí mo hù gẹ́gẹ́ bíi olórí ológun- Buhari













