Ilé aṣòfin àgbà láwọn ṣetán láti buwọ́lù owóyàá $29.96bn fún ìjọba Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, NgrSenate
Aarẹ Ile Aṣofin Naijiria ti fidi ọrọ mulẹ pe awọn aṣofin yoo buwọlu owoyaa ọgbọn biliọnu dọla din diẹ ti aarẹ Buhari kowe si wọn fun.
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ nilu Abuja ni o fi ọrọ yi lede.
Ahmed Lawan ni ko si iye meji lori boya awọn yoo buwọlu owo naa fun ẹka iṣejọba Naijiria.
Ile aṣofin to ṣaaju eleyi ti kọkọ tako erongba ijọba lati ya owo yi lọdun 2016.
Idi ti wọn fi ṣe bẹẹ ni pe wọn ijọba ko ṣọ ẹkunrẹrẹ alaye lori idi to fi fẹ ya owo naa.
Amọ bayi Ahmed Lawan ti ni yoo ṣeeṣee.
O ni ''ti a ko ba lowo ti a si ni iṣẹ agbaṣe to yẹ ka ṣe, nibo la ti fẹ́ ri owo pese awọn ohun amayedẹrun?''
Esi ti aarẹ ile asofin agba fọ yi ti dẹkun ọrọ iyemeji to n waye boya ile yoo tako yiya owo yi tabi ki wn gbaa wọle.
Bi a ko ba gbagbe laipẹ yi ni awuyewuye bẹ silẹ lori ipinnu ijọba lati ya owo yi ti yoo mu ki gbese ti Naijiria jẹ ja si aadọta biliọnu dọla.
Pupọ awọn ẹgbẹ alatako ati awọn ọmọ Naijiria ni wọn bu ẹnu atẹ lu yiya owo yi.
Ṣẹnẹtọ nigbakan ri Sani Shehu tilẹ sọ pe arọmọdọmọ Naijiria ni yoo ba ninu gbese owo yi.
Ahmed Lawan tubọ ṣalaye pe awọn yoo tọpinpin bi ijọba ba ti ṣe fẹ na owo yi ki o ba le ṣe anfaani fara ilu.












