Internet: Ìpínlẹ̀ Oyo ni yóò kọ́kọ́ jànfàní òpó ìtàkùn àgbáyé

Oríṣun àwòrán, iStock
Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ni awọn n pinu lati ya iye owo ọgọrun miliọnu dollar lati orilẹede India
Owo yiio ni ijọba ni awọn fẹ lo fun idagbasoke itakun agbaye to fi mọ ẹrọ ayelujara ninu ilu ati lẹyin odi.
Minisita fun ibaraẹni sọrọ, Adebayo Shittu kede eleyii lọjọbọ nibi eto ajọṣepọ awọn amoju ẹrọ eyi to waye nilu Abuja.
Ohun ti awọn ọmọ Naijiria n sọ ni pe kii ṣe igba akọkọ niyi ti orilẹede Naijiria yoo lọ ya owo lọwọ orilẹede miiran pẹlu fifi eto idagbasoke boju.
Shittu sọ pe owoyaa naa wa lara biliọnu mẹwa dollar eyi ti orilẹede India la kalẹ fun awọn orilẹede ilẹ Afirika lati ṣeranwọ fun oniruuru iṣẹ akanṣe ti wọn nii ṣe.
O ni, lorilẹede India, gbogbo eniyan lo wa lori itakun to lu ja ara wọn ṣugbọn idakeji rẹ lo wa lorilẹede Naijiria ti ko tilẹ tii kọja ida ọgbọn ninu itakun to lu jara.
Aṣoju orilẹede India ni Naijiria, Abhay Thakur sọ pe bi India ba le fọwọ si ẹyawo naa, wọn yoo bẹrẹ ipele ikinni riri awọn opo itakun agbaye naa mọlẹ lakọkọ ni ipinlẹ Oyo ki wọn to gbe e lọ si awọn ipinlẹ to ku.
Ko i tii pẹ l titi ti orilẹede Naijiria tun ya owo aadọjọ miliọnu dollar lati fi san owo akanṣe iṣẹ ipese ina lorilẹede yii.













