Nigeria Elections 2019: Wọ́n yàn-án ní gómìnà, àmọ́ orí gbé e dé ipò igbákejì ààrẹ

Oríṣun àwòrán, @AtikuOrg
Ọjọ Kẹẹdọgbọn Osu Kọkanla ọdun 1946, eyi tii se ọdun mejilelaadọrin sẹyin, ni Garba Atiku ati Aisha Kande Abubakar se ọlọkọ ọmọ tuntun jojolo kan de ile aye.
Ilu Jada nipinlẹ Adamawa si ni ẹjẹ ọrun naa fi ori sọlẹ si, eyi ti wọn pe suna rẹ ni Atiku Abubakar.
O se ni laanu pe ọmọde yii ko ju ọdun mọkanla lọ, to fi di ọmọ alaini baba, ti iya rẹ si jade laye ldun 1984.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Fun awọn eeyan miran, wọn bi wọn sile ọla ni, wọn ba ọla nile tabi de ba ọla, sugbọn ni ti Atiku Abubakar, ọmọ atapata dide ni, to si sisẹ pẹlu ọwọ rẹ mejeeji ko to de ipo ọla.

Oríṣun àwòrán, @Atiku
Gẹgẹ Atiku ti se akọsilẹ rẹ, o ni oju oun ri to nigba ti oun wa ni kekere, tori ọmọ ti ko ni baba lo dun fi iya jẹ. Ọdọ baba baba oun si ni oun gbe dagba, bẹẹ si ni isẹ ati osi ko jẹ ko lee setọju oun bo se yẹ, ọjọ tawọn si fi ebi sun lo pọ, nigba ti ounjẹ ẹẹkan lojumọ mọ awọn lara.
Awọn ile ẹkọ wo ni Atiku lọ?
Bi o tilẹ́ jẹ pe baba rẹ ko fẹ ko ka iwe oyinbo, sibẹ o lọ sile ẹkọ alakọbẹrẹ Jada lọmọ ọdun mẹjọ, to si lọ sile ẹkọ Adamawa Provincial Secondary School, Yola lọdun 1960.
Lẹyin eyi ni Atiku jẹ anfaani ẹkọ ọfẹ lọdun 1967 lati tun lọ kẹkọ siwaju nile ẹkọ fasiti Ahmadu Bello nilu Zaria, to si gba iwe ẹri Diploma ninu imọ ofin.

Oríṣun àwòrán, @Atiku
Atiku Abubakar ti sisẹ gẹgẹ bii osisẹ asọbode ri, to si lo ogun ọdun nibẹ. Koda o di igbakeji oludari agba fun ileesẹ naa, eyi to jẹ ipo to ga sikeji.
Osu Kẹrin ọdun 1989 lo fẹyin ti lẹnu isẹ, to si di olokoowo ati oloselu paraku.
Alagbo nla ni idile Atiku Abubakar
Atiku pade omidan Titilayọ Albert lasiko ti isẹ gbe lọ si Idi Iroko bii asọbode, ti wọn si se igbeyawo bonkẹlẹ losu kejila ọdun 1971 nilu Eko, nitori mọlẹbi Titilayọ tako igbeyawo wọn.
Ọjọ kẹrindinlọgbọn osu kẹwaa ọdun 1972 ni wọn bi ọmọbinrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Fatima, ti wọn si tun bi Adamu, Halima ati Aminu tẹle.
Lọdun 1979 ni Atiku tun fẹ Ladi Yakubu bii iyawo keji pẹ́lu alaye pe, oun fẹ di alagbo nla nigba to jẹ pe oun nikan poloro lawọn obi oun bi. - Abba, Atiku, Zainab, Ummi-Hauwa, Maryam ati Rukaiyatu.

Oríṣun àwòrán, @Atiku
"Awọn iyawo ati awọn ọmọ mi ni ara, oludamọran ati ọrẹ ti mo ni." Ọmọ mẹfa si ni Ladi bi fun - Abba, Atiku, Zainab, Ummi-Hauwa, Maryam ati Rukaiyatu.
Rukaiyatu ni iyawo kẹta, o si bi Aisha, Hadiza ati Aliyu, nigba ti Fatima Shettima si jẹ iyawo kẹrin, ẹni to bi Amina, Mohammed ati Ibeji - Ahmed ati Shehu, Zainab ati Hafzat.
Aarin oun ati Ladi daru, ti wọn si kọ ara wọn silẹ, lẹyin eyi lo wa fẹ Jẹnnifer.
Irinajo Atiku lagbo oselu
Atiku ti kopa ninu ibo abẹnu fun ipo gomina lọdun 1991 nipinlẹ Gongola ijọun ( tii se ipinlẹ Adamawa ati Taraba bayii ), to si tun kopa ninu ibo abẹnu fun ipo aarẹ ilẹ wa lọdun 1993 ninu ẹgbẹ oselu SDP tijọba ti fofin de, to si se ipo kẹta lẹyin oloye MKO Abiọla ati Babagana Kingibe.
Amọ lọdun 1998 ni Abubakar Atiku jawe olubori lati di gomina ti ilu dibo yan labẹ asia ẹgbẹ oselu PDP. Sugbọn ko to gba ọpa asẹ ni aarẹ tilu dibo yan nigba naa, Oloye Olusẹgun Ọbasanjọ ba yan-an gẹgẹ bii igbakeji rẹ.

Oríṣun àwòrán, @Atiku
Ni saa keji isejọba awọn asaaju mejeeji naa, ni esu tapo si aarin wọn, ti ikunsinu ati aawọ si bẹ silẹ, eyi to se akoba nla fun igbiyanju Atiku lati dije fun ipo aarẹ orilẹede yii.
Lọwọ lọwọ bayii, Atiku Abubakar ni oludije fun ẹgbẹ oselu PDP, ti yoo si gbe asia ẹgbẹ oselu naa ninu idibo ti yoo waye losu keji ọdun 2019
Atiku nifẹ lati ran mẹkunnu lọwọ
Ẹlẹyinju aanu ni Atiku, to si maa n fi owo saanu fun awọn eeyan to nilo rẹ. Idi ree ti wọn se fi jẹ oye Turaki ati Waziri ti Adamawa.
Atiku ni aya mẹrin, to si bi ọmọ mejidinlọgbọn.

Oríṣun àwòrán, @Atiku
#BBCNigeria2019













