Atiku Abubakar: A ó rántí Ààrẹ Buhari fún ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìtàjẹ̀sílẹ̀ lásìkò rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Twitter/@Atiku
Igbakeji Aarẹ tẹlẹri, Atiku Abubakar ti sọ wi pe awọn eniyan ko ni gbagbe isejọba Aarẹ Muhammadu Buhari nitori ọgọọrọ itajẹsilẹ to waye lasiko isejọba rẹ.
Atiku sọ eyi nibi ipolongo gbogboogbo to ti se afihan ipinnu rẹ ni ilu Adamawa ni Yola, lati dije du ipo Aarẹ ninu idibo gbogboogbo ti yoo waye niọdun 2019.
Oludije naa to buẹnu atẹ lu isekupani ọlọgọọrọ to n waye ni awọn agbeegbe kan lorilẹede Naijiria, fi ẹsun kan isejọba Buhari wi pe ọpọ eniyan lo ku ni asiko rẹ.

Oríṣun àwòrán, Twitter/@Atiku
Amọ, ọpọ eniyan lo ti fi ẹsun kan igbakeji aarẹ tẹlẹri naa lori ẹsun iwa ibajẹ ati iwa ajẹbanu ni awujọ.









