Shehu Sani: Irandiran àwọn ọmọ Naijiria ni yóò má a san gbèsè owo tí Buhari bá yá

Oríṣun àwòrán, BUHARI SALAD
Alaga tẹlẹri fun eto owo yiya labẹle ati lokeere ni ile igbimọ asofin to kọja, Sẹnatọ Shehu Sani ti bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu igbesẹ Aarẹ Buhari lori bi o ṣe kọwe si Ile Igbimọ Asofin lati buwọlu igbesẹ oun lati ya ọgbọn biliọnu Naira lọwọ ilẹ okeere.
Shehu Sani ti wa ni Ile Igbimọ Asofin labẹ aarẹ tẹlẹri Bukola Saraki.
O ni Aarẹ Buhari ti kọkọ sọ wi pe oun fẹ ya owo lasiko Saraki ni eyi ti awọn si fi owo osi da a nu wi pe ko tọna nitori owo ti wọn jẹ silẹ tẹlẹ ti pọju.
Sani ni ti Ile Igbimọ Asofin to wa ni aleefa bayii ba gba lati jẹ ki Aarẹ Buhari ya owo naa, owo ti Naijiria je yoo aadọta biliọnu dọla owo ilẹ okeere, eleyii ti yoo fa ipalara fun idagbasoke orilẹ-ede Naijria.
O ni nigba ti isejọba Aarẹ Muhammadu Buhari bẹrẹ ni ọdun 2015, Naijiria jẹ gbese to to biliọnu mẹwaa naira.
Bakan naa ni Aarẹ Buhari ya biliọnu mẹwaa dola, eleyii to ni o fi jẹ ogun biliọnu nigba naa.

Oríṣun àwòrán, @SHEHUSANI
O wa fikun un wi pe ti Aarẹ Buhari ba tun ya ọgbọn biliọnu ti o fẹ ya, irandiran awọn ọmọ Naijiria ni yoo san owo naa.
Amọ Aarẹ Buhari ni oun nilo lati ya owo naa ki awọn le e pari gbogbo iṣẹ akansẹ ti oun ti dawọ le ni saa yii.
Aarẹ Buhari ni iṣẹ akanṣe naa yoo ṣeranwọ fun ẹka iwakusa, ina mọnamọna, eto ilera, eto ọgbin, ipese omi ati eto ẹkọ to gbooro fun awọn ọmọ Naijiria.
Amọ, sẹnatọ Sani ni eleyii ti wọn ti ya tẹlẹ ri, ki ni wọn ti fi ṣe? ati wi pe ṣe igbe aye awọn eniyan ti dara si abi bẹẹ kọ?
Aarẹ Buhari lo n beere pe ki awọn aṣofin fọwọ si igbesẹ to fẹ gbe lat ya owo biliọnu ọgbọn dọla lati ilẹ okeere ko le fi ṣe awon iṣẹ aknṣe to pọ.















