EFCC: Ọ̀gá ẹlẹ́wọ̀n àti dókítà gba ẹlẹ́wọ̀n láàyè láti kúrò láhàmọ́ọ́ fún ìtọ́jú

Oríṣun àwòrán, EFCC
Ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra ni Naijiria EFCC ti kede pe oun ti mu ọga awọn oṣiṣẹ ẹlẹwọn Kirikiri nilu Eko nitori pe o ṣe iranwọ iwe aṣẹ ayederu fun ẹlẹwọn kan lati gba itọju nile iwosan.
Emmanuel Oluwaniyi to jẹ ọga agba awọn ẹlẹwọn ati Hemeson Edson Edwin to jẹ dokita to n mojuto ilera awọn ẹlẹwọn ni EFCC sọ pe, aje iwa ibajẹ ṣi mọ lori.
Lọjọ Aje tii ṣe ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Kọkanla ni ajọ naa ni awọn oṣiṣẹ awọn mu awọn mejeeji.
Wilson Uwujaren to jẹ agbẹnusọ Ajọ EFCC sọ pe, awọn mejeeji buwọlu iwe aṣẹ to fun ọgbẹni Hope Aroke lanfaani lati lọ gba itọju nile iwosan nita ọgba ẹwọn.
Igbesẹ wọn yi ni EFFC sọ pe o ṣi ọna fun Aroke lati hu orisirisi iwa gbajuẹ lasiko to yẹ ko wa lọgba ẹwọn pẹlu iranwọ awọn ọdaran mii.
O ni awọn mejeeji ti n ṣwi tẹnu wọn fajọ EFCC.
Bi a ko ba gbagbe, laipẹ yi ni iroyin kan pe ọgbẹni Hope Aroke ti wọn tun un pe ni H Money n wọke lati inu ọgba ẹwọn ti wọn fi si.
Koda iye owo gbajuẹ to n ṣe lati inu ẹwọn la gbọ pe o to miliọnu dọla kan.
Aroke ti ile ẹjọ ti dajọ ẹwọn ọdun mejila fun ni ajọ EFCC sọ pe o tun n da ọran mọ ọran ninu ọgba ẹwọn ti wọn fi si.












