Kidney Transplant: Ilé ìwòsàn ṣ'àṣìṣe ṣiṣẹ́ abẹ kìndìrín fún aláìṣàn ní New Jersey

Ifun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Kidney Transplant: Ilé ìwòsàn ṣ'àṣìṣe ṣiṣẹ́ abẹ kìndìrín fún aláìṣàn ní New Jersey

Eleyi maa gbẹnutan! Ile iwosan kan niluu New Jersey lorilẹ-ede Amẹrika lo ṣaṣiṣe fun ẹnikan kindirin ti kii ṣe tiẹ.

Ẹlomiiran to n jẹ orukọ kan naa ti ọjọ ori wọn ko jina si ara wọn ni wọn fẹ parọ kindirin rẹ kawọn dokita naa to lọ fun ẹni ko ni aarun kindirin.

Nigbẹyin gbẹyin, awọn mejeeji ni ile iwosan Virtua Our Lady of Lourdes ni Camden parọ kindirin wọn, koda ile iwosan ni ara awọn mejeeji ti bọ wa s'ipo bayii.

Lọjọ keji ti wọn ṣiṣẹ abẹ naa tan ni ile iwosan naa ṣẹṣẹ mọ pe aṣiṣe ti waye lori ẹni ti wọn parọ kindirin rẹ.

Awọn alaṣẹ ile iwosan naa ni iru rẹ ko ṣẹlẹ ri lati igba ti wọn ti da ile iwosan naa silẹ.

Igbakeji aarẹ ile iwosan naa to tun jẹ olori awọn dokita nibẹ, Reginald Blaber sọ pe iru aṣiṣe bayii ko wọ pọ rara.

ile iwosan

Oríṣun àwòrán, @Virtua Health

Àkọlé àwòrán, Oto leni ti won fe fun ni kindinrin, oto ni eni ti won sise fun

Amọ, Blaber ni o yẹ ki ayẹwo finifini le dena aṣiṣe yii, bo tilẹ jẹ pe iru rẹ ko wọ pọ.

Eeyan bi ẹgbẹrun un mẹtalelaadọfa ni ile iwosan naa fẹ ṣiṣẹ abẹ pipaarọ kindirin fun gẹgẹ bi iroyin ti wọn fi sita lori oju opo itakun agbaye wọn.

Àkọlé fídíò, Yorùbá tone mark: Fífi àmì ohùn sí orí ọ̀rọ̀ Yorùbá ṣe pàtàkì

Bayii, wọn ti tun iṣẹ abẹ pipaarọ kindinrin fun ẹni ti wọn fẹ ṣee fun gangan lọsẹ to tẹlee.

Adari awọn oniṣegun oyinbo naa ni pe ẹni ti wọn kọkọ fun ni kindinrin tuntun naa nilo kindinrin ṣugbọn ko si lara awọn torukọ wọn wa loke pe asiko ko pọ fun mọ.

Ile iwosan naa kọ lati fi orukọ awọn mejeeji sita.

Ile iwosan Virtua Our Lady of Lourdes yii nikan ni wọn ti n ṣe iṣẹ abẹ paṣipaarọ kindinrin, ọkan ati awọn iṣẹ abẹ bẹẹ miran ni guusu New Jersey.

Àkọlé fídíò, Cancer: Àṣe ara mi ni iso ti n run gbogbo bí mo ṣe n ṣèrànwọ́ lórí jẹjẹrẹ