Plea Bargain: Agbẹjọ́rò ní apanìyàn nìkan ní kò le è bẹ̀bẹ̀ láti dá ẹ̀mí tó pa padà

Abdullahi

Oríṣun àwòrán, Pulse

Àkọlé àwòrán, 'Olóṣèlú o, ọ̀dọ́ o, afurasí o, kò sẹ́ni tí kò lè dúnàá dúrà "ẹ má fi mí jófin'

Laipẹ yii, ọpọlọpọ iwa jibiti, jẹgudujẹra, lilu owo ilu ni ponpon tabi ṣiṣe e baṣubaṣu wọ pọ lorilẹede Naijiria, ti ijọba si n fi awọn eeyan kanjofin.

Ẹwẹ, bi a ba gbe e yẹwo laarin gbogbo awọn ti igba iwa yii n ṣi mọ lori pẹlu iṣọri wọn lawujọ, yala agbalagba oloṣelu tabi ọdọ,awọn ti ko ṣe oṣelu lo wọpọ.

Asa "Ẹ dákun mo jẹbi ẹsún ẹ jẹ́ki a jọ ṣe adéhùn" jẹ ǹkan to máa n wáye lásìkò ìgbéjọ ti olùjẹ́jọ ba gbà pe òun jẹ̀bi ẹsùn ti wọ́n fi kan òun.

Eyí jẹ ǹkan to wáye lásìkò ti wọ́n ṣe ìdájọ Abdullahi Dikko, to jẹ ọga aṣọ́bode tẹ́lẹ̀rí ti ilé ẹjọ́ to ga jùlọ l'Abuja si paa lásẹ pe, ajọ tó n gbógùn ti ìwà jẹgudújẹra ní Nàìjíríà kò lẹ́tọ̀ọ́ láti gbe lọ si ilé ẹjọ́ mọ.

Gẹ́gẹ́ bi adájọ àgbà Nnamdi Dimgba ṣe sọ, níwọ̀n ìgbà ti olùjẹjọ náà ti pa iléri rẹ̀ mọ láti dá Bílíọnù kan àbọ̀ naira pada, nítori naa ko si ẹni to le gbe lọ si ilé ẹjọ́ mọ́.

Èyí ló mú kí àwọn ọmọ Naijiria máa kọ ha pe, kí lo fi sorí tí ẹlòmiran o ṣe, kí ní ìdí ti Dikko kò fi ní ṣẹ̀wọ̀n.

Ilé iṣẹ́ BBC bá agbẹjọ́rò Tayo Fatogun sọ̀rọ̀ láti mọ ẹni to le ṣe àdéhùn idunadura lasiko ẹsẹ ikowojẹ.

Àkọlé fídíò, 'Buns ni ọmọ mi jẹ tán ní ṣọ́ọ̀ṣì, ló bá di àwátì'

Tani ó ni oré-ọ̀fẹ́ Mo jẹbi ẹ̀sùn ẹ jẹ́ kí a ṣe adéhùn:

  • Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, àsìkò ìgbẹ́jọ ni olùjẹ́jọ le bẹbẹ mo jẹbi ẹsùn
  • Olùjẹ́jọ yóò jọ́wọ̀ àwọn ǹkan ti wọ́n ba ni o jí fún ìjọba
  • Agbẹ́jọ́rò àgbà náà ni aṣẹ̀ láti gbé ẹ̀sẹ̀ lé ẹjọ to ba wùú
  • Àjọ EFCC kò ní agbára láti pinu irú ìjìyà ti o tọ́ si ọ̀dáràn àyàfi ti agbẹjọ́rò àgbà ba gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀
  • Àdéhùn gbọ̀dọ wà láàrin àwọn agbẹjọ́rò àgbà àti ẹnikẹni tó ba ń bá ọdaran ṣẹjọ
  • Tí ìjọba ba ri pé ìgbésẹ̀ náà dín ináwó kù, o dí àsìkò ti yóò sòfò kù, nítori pé kò rọrùn láti ṣe ẹjọ o si maa n gba àsìkò púpọ.
  • Olùjẹ́jọ ní yóò kọkọ tọ ilé ẹjọ lọ́ laáti bẹ̀bẹ̀ pé mó jébi ẹsùn yìí ẹ jẹ ki a jọ wọ́ inú àdéhùn lọ
  • Kí ènìyàn tó le lọ bẹ̀bẹ̀ fún adéhùn, o ṣe pàtàkì ko ni ǹkan to fẹ́ dá pada
  • O pọ́ndandan pẹ̀lú latí kọ́kọ́ dé ilé ẹjọ ki olùjẹ́jọ sí

Pẹ̀lú gbogbo àlà silẹ̀ yìí, Agbẹ́jọrò Tayo Fatogun ni pe, o túmọ si pé kò sí ẹniti kò le bèèrè fún mo jẹbi ẹsùn , sùgbọ́n ẹ jẹ ki a ṣe adéhun àti pe mo ṣetan láti dá ǹkan to mo jí pàda.

Amọ o ni eyí le maa le ṣeṣe fún ẹní to pa ènìyàn nitori ko le ni ore-ọ̀fẹ́ láti dá ẹmi ènìyàn pada.