Estonia pàdánù owó gọbọi látàri Eku tó gba ìjọba ní Estonia

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orilẹ-ede Estonia lo wa ni ariwa ilẹ Yuroopu.
Estonia jẹ orilẹ-ede ti wọn ti goke agba ninu ọna igbalode nipa ṣiṣe gbogbo nkan inu eto ọrọ aje wọn ni eyi ti wọn fi n lo ayelujara pupọ.
Ọpọlọpọ idunadura awọn eniyan Estonia lo jẹ pe ẹrọ ayarabiaṣa kọmputa ni wọn n lo fi ṣee.
Ọpọ wọn ni kii kuro lojukan ti wọn wa ki wọn to ṣeto karakata oojọ wọn ni Estonia ṣugbọn eku ti ṣe akoba nla fun eto ọrọ aje wọn bayii.
Ọpọlọpọ igba lawọn oniṣẹ ibi lori ayelujara ti n fẹ doju eto ọrọ aje Estonia ru tẹlẹ ṣugbọn ti ko ṣeeṣe fun wọn nitori pe ijọba Estonia ni igbesẹ idaabobo to dara.
Ori ayelujara ni wọn ti n dibo, ti wọn tun ti n san owo orí ninu eyi ti Banki agbaye ti fi kede pe orilẹ-ede Estonia jẹ ọkan lara awọn orilẹ-ede perete lagbaye to n lo ayelujara julọ.
Ṣugbọn si iyalẹnu gbogbo eniyan, eto okowo ti awọn eniyan ko ri bajẹ ni eku ti yi pada ni Estonia.
Ṣaa deede ni wọn rii pe gbogbo nkan dojuru nigba ti ajọ State Information System Agency (RIA) si bẹrẹ iwadii ni pẹrẹwu.
Ninu iwadii wọn ni RIA ti rii pe awọn ekute lo ṣọṣẹ fun awọn waya ti wọn ri mọlẹ kaakiri ni eyi to jẹ ki awọn irin iṣẹ Estie digital services portal da iṣẹ silẹ ni orilẹ-ede Estonia.
Iṣẹ buruku tawọn eku yii ṣe si awọn waya ni Estonia pọ de ibi pe ko ṣeeṣe fawọn dokita lati kọ oogun fawọn alaisan.
Bakan naa ni ko ṣeeṣe lati mọ awọn to jawe olubori ninu idije tẹtẹ to gbayii nibẹ lasiko yii.

Oríṣun àwòrán, @Toomas
Loru mọju ni wọn ti tete paarọ waya oni mita ọọdunrun ni agbegbe Harju ni olu ilu Tallinna ti wọn si ti bẹrẹ iṣẹ atunṣe awọn
Kaido Plovits to jẹ ọga agba fun ajọ RIA ṣalaye pe ko pẹ ti wọn pari atunse yii ni kia ni eyi ti ohun gbogbo dẹ ti bẹrẹ pada.

Oríṣun àwòrán, @Eesti.ee
O ni inu wọn dun pe iṣẹlẹ yii ko da akọsilẹ idanimọ awọn olugbe Estonia lori ayelujara ru tabi ko ba nkan jẹ ju bayii lọ.
Plaovits ni iṣẹ ṣi n lọ lati dabo to yẹ bo awọn waya yii lọwọ eku ki iru iṣẹlẹ yii ma le ṣẹlẹ mọ.














