Ìjọba Zamfara wọ́gilé owó ìfẹ̀yìntì tàbùà tabua fawọ̀n Gómìnà

Gomina Matawalle

Ile aṣofin ni ipinlẹ Zamfara ti wọgile owo ifẹyinti ti ijọba ana nipinlẹ naa ṣagbekalẹ rẹ fun Gomina ati igbakeji rẹ.

Gẹgẹ bi atẹjade kan ti olori ile aṣofin naa Mustapha Jafaru fi sita lọjọ Iṣẹgun, awọn aṣofin naa sọ pe lati wakati yii lọ ko ni si owo ifẹyinti ati awọn ajẹmọnu miiran mọ fun Gomina ati igbakeji rẹ.

Aba naa ti olori ọmọ ẹgbẹ to pọju lọ nile Faruq Musa Dosara ṣe agbekalẹ rẹ ni o sọ pe yoo dina owo to to ẹẹdẹgbẹrin miliọnu tawọn Gomina n gba lasiko tara ilu n kerora.

Ẹgbẹ oṣelu PDP ni o wa lori alefa ni ipinlẹ naa bayi ti o si jẹ wi pe ijọba APC lo ṣe agbekalẹ ofin yi ki wọn to kuro lori oye.

Igbesẹ Gomina ana Abdulaziz Yari to kọwe si ijọba ki wọn san owo ifẹyinti ti wọn jẹ ohun lo mu gbogbo awuyewuye to pada wa bi iyipada ofin yi waye.

Owo oṣu meji ni wọn jẹ Yari ti o si kọwe pe ki wọn san owo naa fun ohun ni ibamu pẹlu ofin to wa nilẹ.

Àkọlé fídíò, 'Buns ni ọmọ mi jẹ tán ní ṣọ́ọ̀ṣì, ló bá di àwátì'

Esi ti ijọba Gomina Matawalle fi sita ni pe o jẹ iyalẹnu fawọn pe Yari yoo ma beere owo yi nitori ko si Gomina kankan to ti foye silẹ to n kọwe beere owo ti wọn jẹ wọn.

Ni bayi ti wọn ti gbe abadofin kalẹ,ti Gomina Matawaale ba file buwọlu,ko ni si Gomina kankan ti yoo ma gba owo ifẹyinti miran lọdọ ijọba ipinlẹ yatọ si eleyi ti igbimọ to n risi pipin owo oṣu fawọn to fi ipo oṣelu silẹ ba la kalẹ fun wọn.

Pupọ ninu awọn Gomina ipinlẹ Naijiria ni o n gba owo yi ti awọn ile aṣofin la kalẹ ṣaaju ki wọn to kuro lori oye.