Ile aṣofin Kwara da'ba fif'opin s'owo osu ọna meji

Oríṣun àwòrán, TWITTER/ALI AHMAD
Ile igbimọ asofin nipinlẹ Kwara ti fọwọ si aba ofin kan ti yoo dẹkun sisanwo ifẹyinti fun awọn to ba jẹ gomina tabi igbakeji gomina nigba kan ri nipinlẹ naa.
Lara awọn ti ofin naa kan ni enikẹni to ba je gomina tabi igbakeji gomina nigba kan ri ti o si tun di ipo ijọba tabi oṣelu mu lọwọlọwọ.
Lai pẹ yi ni ajọ to n ja fun ifẹsẹmulẹ ẹtọ ọmọniyan (SERAP), gba idajọ nile ẹjọ wipe wọn lẹtọ lati pe awọn asofin ati minista ti wọn figba kan jẹ gomina tẹlẹri ni ipinlẹ , ti wọn si n gba owo ifeyinti pelu owo asofin lọwọlọwọ lẹjọ.
Pataki abadofin yi ni Kwara
Lọdun 2010 ni a atunyẹwo de ba ofin to risi sisanwo ifẹyinti fun awọn gomina lasiko isejọba Dokita Bukola Saraki.
Ofin naa fi aye silẹ ki wọn maa san iye owo osu ti awọn gomina tẹlẹ ba n gba lasiko ti wọn wa lori oye fun wọn gẹgẹ bi owo ifẹyinti leyin ti wọn ba kuro lori oye.
Ofin yi tun fi aye silẹ fun awọn ajẹmọnu orisirisi eyi to kọ ọpọ ẹniyan lominu, paapajulo bo ti se jẹ wi pe awọn gomina kan to fipo silẹ tun lọ gba ipo oselu miran nile asofin agba tabi minista orileede Naijiria.
Awọn ti ofin tuntun yi kan
Bukola Saraki (Aare ile asofin agba).
Kete ti wọn gba aba ofin naa wọle lo ti fo esi si igbesẹ naa loju opo Twitter rẹ:
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Saaju, ki o to di aarẹ ile asofin agba,Saraki jẹ gomina nipinlẹ Kwara fun ọdun mejọ.
Lasiko to fẹ fi ipo silẹ ni ile igbimo asofin ipinlẹ Kwara se agbeyẹwo ofin lori iye owo ifẹyinti fun awọn gomina ati igba keji wọn.
Mohammed Shaba Lafiaji
O ti figba kan jẹ gomina ipinlẹ Kwara lọdun 1992 labẹ asia ẹgbẹ oselu SDP.
O kọkọ wọle si ipo asofin agba nigba ti o jawe olubori gẹgẹ bi asofin to'n soju ẹẹkun ariwa Kwara lọdun 2011.
Lọdun 2015, o tun kopa ninu idibo, to si wole lẹẹkan si.
Lọwọlọwọ,o wa ni ile igbimọ asofin agba orilẹede Naijiria gẹgẹ bi asofin agba.
Se awọn ipinlẹ mi yoo tele igbese yi
Kwara nikan kọ ni awọn gomina wọn ti kuro ni ipo kan bọ si omi.
Awọn gomina nigba kan ri ni ipinlẹ Rivers, Akwa Ibom, Eko, Plateau to fi mọ Ebonyi wa lara awọn to parọ ipo.
Bukola Saraki ti ke si awọn ile igbimọ asofin to ku tọrọ naa kan lati fi Kwara se awokọse.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Amọ saa, aba ofin tuntun yi ko kan awọn ti wọn ba di ipo oselu tabi ti ijọba mu ti wọn ko si gba owo kankan fun ipo ti wọn di mu.













