500 Level Law Student: Ọwọ tẹ afúrasi to pa akẹkọọ fásiti ìpínlẹ̀ Rivers.

Oríṣun àwòrán, Mark/faceebook
Ilé iṣẹ́ ọlọpàá ìpínlẹ̀ Rivers ti mú arakunrin kan ti wọn furasi pe o lọwọ ninu pípa Matilda Itonyo ó n kọ ẹ̀kọ ìmọ ofin onipele karun un ni ìpakúpa ti fasiti Ipinlẹ Rivers.
Afurasí ọhún ti ọlọpàá kò dárúkọ ní wọ́n pè ni ọ̀rẹ́kùnrin ọmọbinrin ti wọ́n ṣekú pa náà.
Iròyìn sọ pé àwọn ọlọpàá tọpasẹ bùba afurasí náà nilé rẹ̀ ni Port Harcourt kìí wọ́n to mu lọ si ilé iṣẹ́ ọlọpàá to ń ri si ìwà ọ̀daran.
Ọ̀bẹ ni wọ́n fi gún ọmọbinrin náà ni ọ̀pọ̀ ìgbá ní ori àti ọrun nílé rẹ̀ ni ìta ọgba fasiti náà.
Ìròyìn fi idí rẹ̀ múlẹ pé, afurasí náà já ilèkùn wọlé ní ìdáji àárọ ọjọ Iṣẹ́gun tó sí fipá báalo pọ ki o tó paa.
Iṣẹ̀lẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bi ẹni to ọ̀rọ̀ náà soju rẹ̀ se sọ pé ó mu àwọn akẹkọọ ipele ti o wà sá kúro ni yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ nígba ti wọ́n gbọ́ nnkan to sẹlẹ̀.
Agbẹnusọ ọlọpàá ni ìpínlẹ̀ ọhún Nnamdi Omoni sàlàye pé àwọn ti mu ọmọkunrin náà fún ìfọ̀rọ̀wanilẹnuwò lóri bí Maltida ṣe kú.
Agbenusọ ni: "A kò le sọ pé a ti mú ẹni to ṣeku pa Maltida ni pato.
A kan mú u láti fọ̀rọ̀wáalẹnúwò ni, ti ìgbá ọ̀rọ̀ náà ba wá ṣi mọ lóri yóò foju ba ilé ẹjọ ti o ba si jẹ ìdàkeji náà ni yoòó maa lọ lálàfíà ti iwadii ba fihan pe ko lọwọ ninu ifipabanilopọ naa ati pipa ọrẹbinrin rẹ nigba kan ri.
Wọn ni oun ati Matilda ti figba kan fẹ ara wọn ri ki wọn to fi ara wọn silẹ.
Bàbá ọmọ ti wọ́n pa, Ebikene Itonyo rọ àjọ ọlọpàá láti tubọ tẹra mọ iṣẹ́ ki àṣírí ẹni tó pa ọmọ náà le tú.














