Cosmic Crisp apple: kò le bàjé nínú ẹ̀rọ amóhun tutù fún ọdún kan

Oríṣun àwòrán, PVM
Èso Apple tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe yìí gba àwọn ónímọ ìjìnlẹ̀ sáyẹnsì ní ogún ọdún láti ṣèwádìí náà yanjú.
Apple náà si le wà nínú ẹ̀rọ amòmítutu fún ọdún kan gbáko ti kò ni bàjẹ, yóò si wọ ilẹ̀ Amerika loníì.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Apple tuntun ọ̀hún ni wọ́n n pè ni Cosmic Crisp, èyí ti wọ́n fi àdàpọ oyin àti òwò ṣe, pẹ̀lú fasiti Washington ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ si ni gbìn láti ọdun 1997
Àfilọ́lẹ̀ èso ẹlẹ́rindòddò yi gba mílíọnù mẹ́wàá dọ́là. (£7.9m)
Ní àsìkò yìí, àwọn àgbẹ̀ láti Washington nìkan lo ní ànfàni lati gbìn èso náà títí dí ọdún mẹ́wàá si àsìkò yìí.
Kate Evans tó wà lárá awọn to dari ọ̀gbìn Cosmic Crisp Apple ní olu ilu orilẹ-ede America sàlàyé pé
"Crisp apple le koko, o ni ọdiwọ̀n àdun àti ilera, bẹ́ẹ̀ lo ni omí dáradára"
Kate fí kún un pé ara apple náà kìí tètè bàjẹ bákan náà ni gbogbo èròjà rẹ yóò pé si lára ti o ba wà nínú ẹ̀rọ amómitutu fún oṣù mẹwàá sí méjìlá.

Igi Cosmic Crisp Apple mílíọnu méjilá ni wọ́n ti gbìn ti iwé àṣẹ̀ rẹ̀ si wà fún àwọn níkan, kò si fi ààyè gba ẹlòmíràn láti gbìn ní apá ibi kankan lọ́rílẹ̀-èdè Amerika.
Washington ló ni ibi ti o tóbi jùlọ ti wọ́n ti n pèsè Apple ni Amẹrika lóniruuru, sùgbọ́n àwọn èyí ti wọ́n ń pè ni Golden Delicious àti Red Delicious ti n ri ìpèníjà pẹ̀lú Pink Lady àti Royal Gala.
Apple ni èso tó n tà julọ lẹ́yìn ọgẹdẹ ní orílẹ̀-èdè Amẹrika.














