Dino vs Adeyemi: Ìyàwó ni Adeyemi lágbo òṣèlú lọ́jọ́kọ́jọ́

Dino Melaye ati Smart Adeyemi

Oríṣun àwòrán, Instagram/Dino Melaye

Àkọlé àwòrán, Ìyàwó ni Adeyemi lágbo òṣèlú lọ́jọ́kọ́jọ́
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ọrọ ko tii tan o lori atundi ibo ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja ti ẹkun iwọ oorun Kogi ninu eyi ti Smart Adeyemi fi fẹyin Dino Melaye gbalẹ.

Melaye ti n sọrọ loju opo ayelujara rẹ lati igba ti ajọ INEC ti kede Ọgbẹni Adeyemi gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu atundi ibo to waye lẹkun naa lẹyin ti Dino ti kọkọ wọle ki ile ẹjọ to wọgile eto idibo naa.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Nigba to n sọrọ loju opo Twitter rẹ, Dino ni iyawo ni Adeyemi jẹ fun oun lagbo oṣelu.

Sẹnẹtọ Melaye ni bi t'ọkunrin t'obinrin ṣe dibo fun oun fihan pe Eleduwa ṣi wa lẹyin oun gbọingbọin.

Ẹwẹ, Sẹnẹtọ Adeyemi naa ṣapejuwe Dino gẹgẹ ọmọ ọdọ ọkunrin rẹ.

Adeyemi ni ''ti ọmọ ọdọ ba ji aṣọ ọga rẹ gbe, aṣọ naa yoo tobi ju lara rẹ, idunnu wi pe oun n wọ aṣọ ọga rẹ lo maa mu un ṣiwa wu sawọn to yẹ ko ṣapọnle fun.''

Sẹnẹtọ Adeyemi ṣalaye pe ''aṣọ alaṣọ ti ko ṣe deedee ti Dino to wọ s'ọrun nigba to wa nile aṣofin agba lo jẹ ko ṣiwawu nibẹ.''

Adeyemi ti ẹgbẹ osẹlu APC ni ibo 88,373 nigba ti Dino to dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP ni ibo 62,133 ninu atundi ibo ọhun.

Melaye ti sọ pe oun yoo gbe ẹjọ idibo naa lọ siwaju igbimọ igbẹjọ to n ri si awuyewuye to jẹyọ ninu eto idibo.

Àkọlé fídíò, Wòólì Alfred kú lọ́dún 1964, ó tún padà wà sí ìlú Agelu f'ọ́jọ́ mẹ́rìnlá!