Benin: UK ṣetán láti dá Adìyẹ 'Àkùkọ' Nàíjìrìa ti wọ́n gbé padà

Benin

Oríṣun àwòrán, PA Media

Àkọlé àwòrán, Adiye 'Akukọ' ti won mo ni egberun odun seyin ni won se setan lati da pada ba yii.

Akukọ gagara ti wọn mọ, ti wọn pe orukọ rẹ ni 'Okukor' ni o da wahala silẹ ni ẹgbẹrun ọdun sẹyin nigba ti wọn ji i gbe lọ kuro lorilẹ-ede Naijiria lọ si Ilẹ Gẹẹsi.

Ile iwe giga, Cambridge University lo kede wi pe awọn yoo da ọkan lara awọn idẹ ti wọn ji ni ẹgbẹrun ọdun ṣẹyin lasiko ti wọn ṣigun bo Naijiria pada.

Ọpọlọpọ ọdun ni o ti wa lowo wọn ko to di wi pe awọn akẹkọọ kan an ni ipa fun wọn lati da a pada si ibi ti wọn ti gbe e wa.

Bangwa Queen

Oríṣun àwòrán, DAPPER FOUNDATION

Àkọlé àwòrán, Benin: UK ṣetán láti dá Adìyẹ 'Àkùkọ' Nàíjìrìa ti wọ́n gbé padà

Ile iwe giga naa ni Ọba ilu Benin lo ni i, ati wi pe ibe ni wọn ti gbee wa, amọ wọn ko sọ igba tabi akoko ti wọn yoo da a pada.

Lara awọn ohun ẹṣọ abalaye ti awọn ara Benin mọ ni ọkan lara aworan adiyẹ ide ti Ilẹ Gẹẹsi fẹ da pada yii.

Lasiko ti Ilẹ Gẹẹsi kọ Naijiria lẹru, ọ le ni ẹgbẹẹgbẹrun awọn ohun abalayẹ ti wọn ko lọ.

Bakan naa ni wọn si sọ wi pe awọn yoo da lara rẹ pada.

Amọ wọn ṣeleri pe awọn yoo ya Ajọ Nigerian Royal Museum ni lara wọn, ti yoo bẹrẹ iṣẹ ni ọdun 2021.

Maqdala Treasures

Oríṣun àwòrán, V&A MUSEUM

Àkọlé àwòrán, Bakan naa ni wọn si sọ wi pe awọn yoo da lara rẹ pada.

Igbesẹ Ilẹ Gẹẹsi yii farapẹ igbesẹ awọn orilẹ-ede miran ni ilẹ Europe ti o ti pinnu lati da awọn ohun abalaye to jẹ ti ilẹ Afrika amọ ti wọn jigbe pada si ibi to yẹ.

Aarẹ ilẹ Faranse, Emmanuel Macron sọ wi pe laarin ọdun mẹrin ni oun yoo da gbogbo rẹ pada fun Afrika.

Àkọlé fídíò, Ogun Cholera: Ọdọọdún ni àrùn onígbá-méjì máa n ṣọṣẹ́ ní Nàìjíríà-NCDC