Border Closure: Mínísítà fétò ìṣúná ní fún ìgbà díẹ̀ ni wọn yóò fi ti ẹnu bodè pa

Oríṣun àwòrán, @finance
Ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari ti ni lootọ ni pe ibode ti awọn ti lo fa ki owo ọja o gbe pẹẹli soke si.
Minisita fun eto isuna orilẹede Naijiria, Abilekọ Zainab Ahmed lo sọ bẹẹ lẹyin ipade igbimọ alasẹ ti ijọba apapọ, Federal Executive Council ni ilu Abuja.

Oríṣun àwòrán, @anaedoonline
Ahmed sọ eyi lasiko ti awọn akọroyin n beere lowo rẹ lori igbeṣẹ ijọba lori ibode ti wọn ti pa.
O ni lootọ ni pe, ọwọngogo ounjẹ ti mu ki owo ọja gbe owo lori kaakiri orilẹede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Others
Amọ, o fikun wi pe, ijiroro nlọ lọwọ pẹlu awọn orilẹ-ede to sumọ Naijiria lati bọwọ fun ofin katakara ti yoo mu ki ibasepọ to gbooro wa laarin awọn orilẹ-ede nilẹ Afirika.
Minisita fun ọrọ eto isuna naa ni, fun igba diẹ ni ọrọ ibode ti awọn ti naa, lati dẹkun magomago ti awọn orilẹ-ede to sunmọ ibode Naijiria n se lati gbe ọja wọle ni ọna aitọ.









